Ọpọ eeyan lo n ṣe ni kayeefi nigba ti wọn ri opopona tuntun ti ijọba ipinlẹ Kwara ṣẹṣẹ pari rẹ lawọn agbegbe bii Akanbi Oke to wa lopopona Taiwo, Oko Erin ati Adisa Bakare to yọ si Kuntu.
Awọn agbegbe yii ni ko sẹni to lero rẹ wi pe ọda ijọba le gbabẹ kọja.
Opopona igbalode ti wọn n fi simẹnti yọ, iyẹn interlock ni ijọba ṣe awọn agbegbe yii, pẹlu erongba lati le jẹ alalopẹ.
Igbesẹ yii jẹ ọkan lara awọn erongba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati sọ igbẹ dilu, ati igbo di igboro, fun irọrun ati igbayegbadun araalu.
Eyi yoo tun jẹ ki irọrun wa fun igbokegbodo ọkọ araalu, lai daamu bii ti tẹlẹ.
No comments:
Post a Comment