Ọmọwe Adetola di oludamọran pataki fun minisita feto ẹkọ ni Naijiria, Gomina AbdulRazaq fidunu han - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 24, 2025

Ọmọwe Adetola di oludamọran pataki fun minisita feto ẹkọ ni Naijiria, Gomina AbdulRazaq fidunu han


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ba oludamọran pataki rẹ lori eto ẹkọ, Ọmọwe Adetola Salau yọ lori ipo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan an fun, gẹgẹ bi oludamọran pataki fun minisita f'ọrọ eto ẹkọ lori eto ti wọn pe ni STEMM and Corporate Sector Engagement.

STEMM ni apeja rẹ n jẹ Science, Technology, Engineering, Mathematics, and Medicine, eyi to wa labẹ akoso ijọba apapọ. 

Gomina AbdulRazaq sọ pe iyansipo naa ba ilana iṣẹ ti Ọmọwe Adetola di mu tẹlẹ lọ, ati pe yoo tubọ jẹ ko maa wa nini ilana, ko si tubọ fi ara jin fun idagbasoke eto ẹkọ STEM lorileede Naijiria ati nilẹ Afrika lapapọ.

“Iwuri nla lo jẹ fun wa nipa awọn aṣeyọri ati ipa to ti ko lori idagbasoke tai ayipada to ti de ba eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, paapaa lẹka ti STEM,” Gomina AbdulRazaq sọ bẹẹ.

“Okun, ọkan ṣiṣiṣẹ papọ ati imọ nipa iṣẹ rẹ jẹ dukia nla to ni. Inu wa dun lati jẹ anfaani ninu awọn ipa to ko lẹka eto ẹkọ wa.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI