Amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode nipinlẹ Kwara, Akewejẹ Olayinka Fafoluyi ti ba Kọmureedi Bisi Fakayode yọ lori bo ṣe di Aarẹ apapọ fun gbogbo Ọmọ Ibilẹ Igbomima kaakiri agbaye.
Akewejẹ Fafoluyi tọpọ tun mọ si Solace ninu atẹjade ikini to fi ranṣẹ si Fakayode ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ Ọmọ Ibilẹ Igbomima laipẹ yii, jẹ ko di mimọ pe igi to tọ ni wọn fi si aaye to tọ, ni asiko to yẹ.
O ni bi Fakayode ṣe jawe olubori lati di Aarẹ agba fẹgbẹ naa, o nii ṣe pẹlu akitiyan ati ipa ribiribi to ti ko ninu idagbasoke ẹgbẹ naa.
Akewejẹ ni lara ohun to tun mu ki Fakayode gbegba oroke ni ifarajin rẹ lati rii pe ẹgbẹ naa ni itẹsiwaju, nipa iwa adari rẹ fun ọjọ pipẹ.
“Inu mi dun gidi lori bi o ṣe jawe olubori gẹgẹ bi Aarẹ apapọ fẹgbẹ Ọmọ Ibilẹ Igbomima, mo si ba ọ yọ lori aṣeyọri nla naa,” Fafoluyi jẹ ko di mimọ bẹẹ.
“Ipo yii jẹ ohun to yẹ lati fi bu ọla fun iru eeyan bii tiẹ, to si jẹ ẹri awọn ifarajin fun iṣẹ isin awọn eeyan, ati paapaa julọ, ipe fun iṣẹ isin ipele giga.” Akeweje stated.
O wa gba ọkunrin naa lamọran lati tubọ lo ipo rẹ fi mu idagbasoke to tayọ kọja ti tẹlẹ ba ẹgbẹ naa.
No comments:
Post a Comment