Akewejẹ kẹdun lori ijamba ina to ṣẹlẹ nile igbimọ aṣofin Irepodun ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 12, 2026

Akewejẹ kẹdun lori ijamba ina to ṣẹlẹ nile igbimọ aṣofin Irepodun ni Kwara


Amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode nipinlẹ Kwara, Akewejẹ Olayinka Fafoluyi, ti ba olori ile igbimọ aṣofin ijọba ibilẹ Irepodun kẹdun lori ijamba ina to waye nile igbimọ aṣofin naa.

Yatọ si olori ile igbimọ aṣofin naa, Ọnarebu Muritala Aliyu Omogoye, o tun ba awọn ọmọ igbimọ aṣofin naa, to fi mọ awọn oṣiṣẹ patapata kẹdun adanu wọn.

Ijamba ina ọhun la gbọ pe o ṣẹlẹ lọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja yii, to si ba ọpọ dukia jẹ, ko to di pe wọn pa ina ọhun.

Nigba to n ba wọn kẹdun ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamẹta, Akewejẹ fi aidunnu rẹ han, to si ṣapejuwe ijamba naa gẹgẹ bi eyi to ba ni lọkan jẹ gidi, nitori ọpọ dukia to ṣofo.

O wa gbe oriyin fun akitiyan awọn eeyan, paapaa awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana, awọn eleto aabo ati ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lori igbesẹ ti wọn fi tete pa ina ọhun.

Akewejẹ ni bi wọn ṣẹṣẹ tete ibi ijamba naa, ti wọn si ṣiṣẹ wọn lasiko, lo fa a ti wọn ṣe tete daabo bo awọn dukia bii awọn iwe to ṣe pataki.

“O jẹ ohun to dunni lọkan lati gbọ nipa awọn ohun ti ijamba ina bajẹ nile igbimọ aṣofin, to si tun sọ ile naa di eyi ti ko wulo,” Akewejẹ sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI