Ileeṣẹ Adron Homes bẹrẹ ipagọ nla lori idagbasoke - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 15, 2026

Ileeṣẹ Adron Homes bẹrẹ ipagọ nla lori idagbasoke


Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited nilẹ Naijiria, Aarẹ Adetola EmmanuelKing ti gba awọn alakoso ati alabojuto ileeṣẹ wọn kaakiri Naijiria lamọran lati maa wa gbogbo ọna ti yoo mu idagbasoke ati itẹsiwaju ba ileeṣẹ ti wọn n ṣoju.

Aarẹ EmmanuelKing lo sọrọ naa nibi ipagọ awọn alakoso ati alabojuto ileeṣẹ naa to n lọ lọwọ.

EmmanuelKing gba wọn lamọran lati pmaa wa gbogbo ọna igbalode ti yoo Lmu imugbooro ba ileeṣẹ naa.

Ipagọ naa ti wọn pe ni 2026 National Business Convention, eyi ti wọn pe akori rẹ ni “Breaking New Grounds, Beyond and Above 2.0.”

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lo ipagọ naa to jẹ ẹlẹẹkeji iru rẹ lati fi ro awọn eeyan naa lagbara, ati lati le ṣe ipinnu pẹlu ilana ọtun fun ọdun 2026, leyi ti yoo mu ileeṣẹ naa gbooro si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI