Akewejẹ tiluu Aran-Orin, Fafoluyi rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati kopa ninu eto iforukọsilẹ to n lọ lọwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 18, 2026

Akewejẹ tiluu Aran-Orin, Fafoluyi rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati kopa ninu eto iforukọsilẹ to n lọ lọwọ

"Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ẹgbẹ wa to ti gbooro, All Progressives Congress (APC) ti bẹrẹ eto iforukọsilẹ ọmọ ẹgbẹ tuntun ati ti tẹlẹ kaakiri Naijiria," Akewejẹ tiluu Aran-Orin, ipinlẹ Kwara, Oloye Michael Olayinka Fafoluyi sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku.

Fafoluyi sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ to ti le ni ẹgbẹrun meji ni wọn ti fi orukọ silẹ kaakiri Naijiria latigba ti eto naa ti bẹrẹ lọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2026.

O ni eto na ti ṣapejuwe bi ẹgbẹ naa ṣe n ni idagbasoke ati okiki to kaakiri ilẹ Naijiria.

Akewejẹ sọ pe ti tẹsiwaju lati maa ṣilẹkun rẹ silẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun lati darapọ mọ wọn, fun ilọsiwaju orileede naa.

"Mo rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ati alatilẹyin ti wọn ko tii forukọsilẹ ninu eto to n lọ lọwọ lati tete fi orukọ silẹ, lati le gbaruku ti iṣakoso Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, ati Gomina AbdulRahman AbdulRazaq," Akewejẹ to tun jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun gomina ipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode rawọ ẹbẹ.

O jẹ ko di mimọ pe kikopa ninu eto to n lọ lọwọ yii ko nii mu imugbooro ba ẹgbẹ naa nikan, bi ko ṣe pe yoo tun ko ipa to jọju ninu ilana eto idibo lọjọ iwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI