Akọni-mọn-ọn-gba ẹgbẹ agbaboọlu Super Eagles, Eric Chelle ti sọ pe gbogbo erongba oun lati fi ẹgbẹ agbaọọlu naa silẹ, kani awọn padanu ipo kẹta ninu idije AFCON to n lọ lọwọ sọwọ akẹgbẹ wọn lati ilẹ Egypt.
O ni yoo jẹ ohun to ṣoro f'oun lati tẹsiwaju gẹgẹ bi akọni-mọ-
ọn-gba Super Eagle bi awọn ko ba yege.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọọmi ni Super Eagles tilẹ Naijiria gba pẹlu akẹgbẹ wọn, Farao lati ilẹ Egypt lọjọ Abamẹta to kọja yii.
Ṣugbọn nigba ato di ipele womi-ki-n-gba-si-ọ, eyi ti a mọ si pẹnariti, ikọ Naijiria fẹyin wọn gbolẹ pẹlu goolu mẹrin si meji.
Igba kẹsan ree ti Super Eagles yoo ṣe ipo kẹta ninu idije AFCON tilẹ adulawọ, Afrika
Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa to waye niluu Casablanca, Chelle sọ pe ọjọ iwaju oun ninu ẹgbẹ naa ko daju, kani oun padanu ni.
“Yoo jẹ ohun to ṣoro fun mi lati tẹsiwaju gẹgẹ bi akọni-mọ-ọn-gba Naijiria, kani a padanu ifẹsẹwọnsẹ naa,” Chelle sọ bẹẹ.

No comments:
Post a Comment