Ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ Kwara jẹ anfaani eto 'Renewed Hope' ti AbdulRazaq ṣefilọlẹ rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 18, 2026

Ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ Kwara jẹ anfaani eto 'Renewed Hope' ti AbdulRazaq ṣefilọlẹ rẹ


Ko din ni awọn ẹgbẹrun lọna igba ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara ti Gomina 
AbdulRahman AbdulRazaq ṣefilọlẹ rẹ lopin ọsẹ to ṣẹṣẹ kọja yii.

Kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa la gbọ pe awọn araalu ti jẹ anfaani ti ko wọpọ yii, eto naa ti wọn fi sọri Aarẹ Bola Ahmed Tinubu tilẹ Naijiria.

Ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide to kọja yii ni Gomina AbdulRazaq ṣe ifilọlẹ eto naa ti wọn pe ni 'Renewed Hope Ward Development Programme (RHWDP)',

Eto naa la gbọ pe Aarẹ Tinubu ṣagbekalẹ rẹ lati fi mu ọpọ ọmọ Naijiria kuro ninu iṣẹ ati oṣi.

Kaakiri wọọdu igba din ni meje (193) ni wọn ti mu gbogbo awọn to jẹ anfaani naa.

Gomina sọ pe lara idaniloju wi pe aarẹ mu ọrọ igbayegbadun araalu lọkunkundun ati lati ṣagbelarugẹ eto ọrọ aje Naijiria lati wọ tiriliọnu kan dọla nigba ti yoo fi di ọdun 2030.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI