Gbogbo eto lo ti pari bayii, fun fasiti ọgbin to wa niluu Abẹokuta, iyẹn Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB), lati bẹrẹ eto ayẹyẹ ikẹkọọgboye ẹlẹẹkẹtalelọgbọn.
Ọsẹ yii ni eto ayẹyẹ naa yoo bẹrẹ lakọtun, gẹgẹ bi awọn alakoso fasiti naa ṣe sọ.
FUNAAB sọ pe ọna ara ni eto ayẹyẹ tọdun yii yoo gba waye nitori oniruuru alakalẹ eto ti wọn ti ṣagbekalẹ rẹ.
Ninu atẹjade ti adele agbẹnusọ fasiti naa, Ọlasunkanmi Ọlajide fi ranṣẹ si GBELEGBỌ, o ni ọjọ Ẹti, ọsẹ yii ni eto ọhun yoo bẹrẹ pẹlu irun Jimọ ti wọn maa ki ni mọṣalaṣi ọgba wọn.
Olajide ṣalaye pe ọga awọn, Ọjọgbọn Oluṣọla Babatunde Kẹhinde nigba to n gba ẹnu gbogbo igbimọ iṣakoso fasiti FUNAAB sọrọ, o ni gbogbo awọn alẹnulọrọ patapata lawọn fiwe pe lati wa ba wọn ṣayẹyẹ ti yoo waye laaarin ọjọ kẹtalelogun si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2026.
O ni eto isin awọn onigbagbọ yoo waye nile ijọsin Chapel of Grace ti FUNAAB, bẹrẹ lati agogo mẹwaa owurọ.
Agbẹnusọ naa tẹsiwaju pe ipade awọn akọroyin yoo waye l'Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn ni gbọngan Red Chambers lagogo mẹwaa owurọ.
Bakan naa lo sọ pe awọn yoo ṣe ifilọlẹ ọpọ awọn akanṣe iṣẹ ti wọn ṣẹṣẹ pari lagogo mẹta ọsan.
"Eto ọlọsẹ kan to fẹẹ waye yii yoo kogba wọle lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii," atẹjade naa sọ bẹẹ.
O sọ pe oniruuru ẹbun lo ti wa nilẹ lati fun awọn to dantọ ninu awọn akẹkọọ wọn fun saa yii.
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe Ọgbẹni Aigboje Aig-Imoukhuede to jẹ alakoso agba ile ifowopamọ Access yoo ṣe idanilẹkọọ fawọn alejo lori akori to pe ni “Integrating Agriculture and Youth Development: A New Paradigm for the Nigerian Education System.”
No comments:
Post a Comment