Ibanilorukọ jẹ lasan lẹsun ti wọn fi kan Ọba MacGregor - Awọn olori ẹbi pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 20, 2026

Ibanilorukọ jẹ lasan lẹsun ti wọn fi kan Ọba MacGregor - Awọn olori ẹbi pariwo sita


Awọn olori ẹbi Ọba Oluṣẹgun Alexandar MacGregor ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti Mutiu Ajibade MacGregor fi kan kabiyesi naa nipa lilo ile mọlẹbi lati fi ṣe aafin rẹ.

Wọn ni ọna lati dabaru eto to wa nilẹ, ati lati da ẹbi ru ni Mutiu Ajibade n wa kaakiri, ati pe asiko to rii pe oun ko le maa fi ile naa gba owo lọwọ kabiyesi lo di pe o bẹrẹ sii purọ kaakiri.

Atẹjade ti ọkan lara awọn olori ẹbi naa, Alaaji Najeem Adesina MacGregor kọ lọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja lorukọ mọlẹbi, eyi ti ẹda rẹ tẹ GBELEGBỌ lọwọ jẹ ko di mimọ pe Mutiu ko le gba ẹnu mọlẹbi sọrọ, debi wi pe yoo maa tako ọba alaye naa.

“Gbogbo mọlẹbi MacGregor ti idilẹ Ọba niluu Ilawọ dide lati tako atẹjade kan to kun fun irọ ati ibanilorukọ jẹ, eyi ti iroyin ori ayelujara kan gbe jade. Ko si ọmọ ẹbi kankan to buwọ tabi fontẹ lu atẹjade naa, ati pe ko jade lati ọdọ wa,” Ẹbi MacGregor sọ bẹẹ.

“Awa mọlẹbi fẹẹ jẹ ko di mimọ pe atẹjade ọhun kii ṣe erongba tabi ajọsọ tabi ipinnu mọlẹbi kankan, bẹẹ si ni ko si ijọkoo mọlẹbi ti wọn ti fẹnu rẹ ko, o si tako ohun ti a duro fun gẹgẹ bii mọlẹbi ọba.

“Siwaju sii, Mutiu MacGregor nikan lo da ọwọ wu lati fi atẹjade naa sita, ẹni to ti n duro funra rẹ lati tako ipinnu gbogbo mọlẹbi, to si n dabaru ifẹ, iṣọkan ati otitọ ti a duro fun, bẹẹ si la ni ko sẹni to fun un laṣẹ lati gba ẹnu mọlẹbi sọrọ.”

Awọn olori ẹbi naa wa ṣalaye pe gbogbo igbesẹ ti Mutiu Ajibade MacGregor n gbe lati ibẹrẹ pẹpẹ ni lati da iyapa silẹ laaarin mọlẹbi, ko le tu ẹbi naa ka, ṣugbọn ti wọn lawọn ko nii gba fun un.

Bẹẹ ni wọn jẹ ko di mimọ pe gbogbo igba lawọn duro fun alaafia, iṣọkan ati ijiroro ti yoo mu itẹsiwaju ba mọlẹbi wọn, kii ṣe lati ba orukọ ẹbi jẹ.

“Ẹbi ọba MacGregor fi ara jin fun alaafia, ijiroro, iṣọkan, ibọwọ fun aṣa ati ọna lati wa iyanju si aawọ, bẹẹ la tun tako gbogbo igbesẹ ẹnikẹni lati wọ orukọ mọlẹbi wa sinu aawọ ti ko nidii, ti ko si lẹsẹ nilẹ.”

Ṣaaju asiko yii la gbọ pe igbimọ oloye ti rọ Mutiu Ajibade loye gẹgẹ bii Bọrọkini ilu Ilawọ lori awọn ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan an, ti wọn lo n da gbogbo eto wọn ru, to si n ba wọn loju jẹ kaakiri.

Iwe ti wọn fi rọ Mutiu loye lọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2026, eyi ti akọwe wọn, Oloye Diyaolu Oluwatosin buwọ lu lorukọ igbimọ naa, lo tẹ GBELEBỌ lopin ọsẹ to kọja yii.

Bakan naa la tun gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun n ba Mutiu jẹjọ ni kootu lori ẹsun marun to nii ṣe pẹlu dida alaafia ilu laamu.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI