Oloogbe naa lo jade laye laipẹ yii lẹyin aisan rampẹ to nii ṣe pẹlu ọjọ ogbo.
Ẹni ọdun marundinlọgọrin (75) ni Imaamu agba naa jẹ ko too ki aye pe o digboṣe lọjọ Aje, oni
Gomina AbdulRazaq nigba to n kẹdun iku oloogbe naa ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi oloro ẹlẹsin to gbe aṣa ati ẹsin Islam larugẹ tọkantọkan.
O lawọn yoo ṣafẹri rẹ gidigidi pẹlu awọn imọ ati oye to maa fi n sọrọ.
Bẹẹ lo ba gbogbo Musulumi kaakiri ipinlẹ naa kẹdun, to si gbadura pe ki Allah tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment