Lẹyin ifẹhonuhan awọn akẹkọọ, Ijọba Kwara rọ ọga ile-ẹkọ 'Kwara Poly' n'ipo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 22, 2026

Lẹyin ifẹhonuhan awọn akẹkọọ, Ijọba Kwara rọ ọga ile-ẹkọ 'Kwara Poly' n'ipo

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti sọ fun ọga agba ile ẹkọ gbogboniṣe tipinlẹ Kwara, Ọmọwe Abdul Jimoh Mohammed lati lọ rọkunle lori wahala to bẹ silẹ nile ẹkọ naa laipẹ yii.

AbdulRazaq ni ki ọga agba naa lọ jokoo sile rẹ titi digba ti iṣẹ iwadii awọn igbimọ to gbe dide lati mọ kulẹkulẹ ohun to fa wahala nile ẹkọ ọhun.

Laipẹ yii ni awọn akẹkọọ ninu ọgba naa dide ifẹhonuhan, lori awọn ohun to n kọ wọn lominu.

Eyi lo mu ki ijọba Kwara gbe igbimọ dide lati ṣe iwadii kikun nipa ohun to ṣẹlẹ.

Igbimọ naa ni Adajọ agba nipinlẹ naa, Onidajọ Senior Ibrahim Sulyman jẹ adari rẹ, nigba ti awọn bii Kọmiṣanna feto ayika, Ọnarebu Nafisat Buge ati akọwe agba Ọmọwe Mercy Olufunkẹ Shittu naa wa ninẹ pẹlu.

Atẹjade ti Hajia Sa'adatu Modibbo Kawu to jẹ Kọmiṣanna feto ẹkọ agba fi sita, o jẹ ko di mimọ pe ọsẹ meji pere ni igbimọ naa ni lati fi ṣewadii ohun to n ṣẹlẹ.

Lẹyin ti wọn ba mọ ohun to n fa ifẹhonuhan, wọn yoo tun sọ awọn ọna abayọ lati dẹkun, ti wọn si tun gbọdọ sọ ọna ti yoo mu idagbasoke ati itẹsiwaju ba ile ẹkọ ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI