Ijọba bẹrẹ atunkọ ile-ẹkọ mẹtala to dẹnukọlẹ nijọba ibilẹ Ariwa Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 22, 2026

Ijọba bẹrẹ atunkọ ile-ẹkọ mẹtala to dẹnukọlẹ nijọba ibilẹ Ariwa Kwara

Lojuna lati amu agbegbe irọrun ba eto ẹkọ, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti buwọ lu atunkọ awọn ile-ẹkọ ijọba mẹtala to ti dẹnukọlẹ nijọba ibilẹ Ariwa ipinlẹ naa.

Igbesẹ yii lo waye ninu eto lati ṣe atunkọ awọn ile-ẹkọ ijọba mọkandinlogoji kaakiri ipinlẹ Kwara.

Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Akewejẹ Olayinka Fafoluyi fi sita, o ni idagbasoke yii ni lati mu irọrun ba eto ẹkọ ati igbayegbadun awọn akẹkọọ ati olukọ.

O ni atunṣe naa yoo fun awọn akẹkọọ ni iwuri lati kẹkọọ lagbegbe ati ayika to dara, ti awọn olukọ naa yoo si tun ni irori gidi nipa ẹkọ ti wọn yoo fi kọ awọn akẹkọọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI