Tiata Ti Mo n Se Ko Di Ise Olopaa Mi Lowo - Biola Best - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 14, 2018

Tiata Ti Mo n Se Ko Di Ise Olopaa Mi Lowo - Biola Best

Okan lara awon gbajumo to sese n dide bo lorileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun, Arabinrin Abiola Edun tawon ololufe e mon on si Biola Best so pe ise tiata toun n se ko di ise olopaa toun tun lo gba lowo nitori pe oun fi aaye sile lati gbajumo ise mejeeji lotooto. Biola soro yi lakoko to n b'AWIKONKO lai pe yi niluu Abeokuta lati fi sori ayeye ifilole fiimu e tuntun to pe akole e ni Odaran Ife, eyi to waye ninu gbongan ayeye ti ile ikawe Obasanjo, iyen OOPL, Abeokuta lojo Sande to koja yi. E ka bi iforowero naa se lo sii.


Biola Best
AWIKONKO: Oruko yin lekunrere?
Biola: Oruko mi ni Abiola Edun tawon eeyan tun mo si Biola Best.

AWIKONKO: Igba wo gan an le bere ise tiata, bawo le se bere?
Biola: Odun 2001 ni mo bere ise tiata. Kekere lo ti wun mi. Odo Yemi Adegunju ni mo ti ko ise. Odun 2003 ni mo gbominira. Okan lara awon fiimu oga mi ni mo wo, to si dun mo mi pupo, eyi lo fa a ti mo fi ronu pe ki n lo sodo e lati ko ise.

AWIKONKO: Nigba ti e maa bere ise tiata, ki le ro debi ki e kose lodo okunrin, ati pe nje e o lero pe nkan min in le teyin e yo gege bi obinrin?
Biola: Ko si nkan to fe e teyin e yo, ko si si nkan to teyin e yo titi dasiko yi, nitori pe nigba ti mo maa bere, emi ati oko mi Badmus Adewale Kazeem la jo bere nigba yen, bo tile je pe ko si nidi ise tiata mo bayii.

AWIKONKO: Iha wo, tabi ka so pe oju wo lawon eeyan yin, iyen awon obi yin fi wo o nigba yen?
Biola: Looto won so pe ki n ma se e, sugbon mi o da won lohun. Nigba ti won ri nkan to sele lojo ti mo se ifilole fiimu mi, inu won dun. Bo tile je pe baba mi ti ku, awon ni inu won ko ba dun ju lojo naa, nitori pe iru nkan be e lawon maa n feran. Inu Maami naa dun lojo naa.

AWIKONKO: A gbo pe e tun n sise olopaa, se looto ni ati pe igba wo le gba ise olopaa?
Biola: Beeni. Sugbon mo ti n sise tiata ki n to o dara po mo ise olopaa lodun 2008. Igba to de aarin kan, awon oga mi nidi ise olopaa ko fun mi laaye lati se tiata daadaa. Won ni mi o le sise min in mo ise olopaa, igba to ya ni mo ko leta sawon oga, ti mo gbe leta naa gba odo alukoro wi pe mo ti n sise tiata ko too di pe mo gba ise olopaa, mi o si tii setan lati fise tiata sile, Olorun si gbo adura mi, to je ki won bu owo luu fun mi pe ki n te siwaju. Leyin ti won ba mi bu owo luu ni mo to o wo lokesan fiimu Odaran Ife.

AWIKONKO: Bawo le se wa n se ti ise mejeeji ko di ara won lowo?
Biola: Olorun ni o. Tiata ti mo n se ko di ise olopaa mi lowo.

AWIKONKO: Ki le fe e so pe o je ipenija gege bi obinrin, paapaa laarin awon okunrin?
Biola: Ko si ipenija kankan, nitori pe bi obinrin ba ni afojusun, to si mo nkan to n se, ko si okunrin kan to le da a laamu, ayafi tiru obinrin bee ba n da ara laamu lo ku. Ko si ipenija kankan fun mi lati odun ti mo ti darapo mo ise tiata.

AWIKONKO: Egbe osere tiata meji lo wa, Ewo gan an leyin n se?
Biola: Egbe osere TAMPAN ni mo wa.

AWIKONKO: Kinni in ajosepo yin pelu awon onise tiata to ku nipinle Ogun?
Biola: Ajosepo to dan monran lo wa laarin wa. A jo n se ipade po, ko si ikunsinu laarin wa. Bi won ba pe mi si ise, maa lo.

AWIKONKO: Bawo ni ajosepo pelu awon ololufe e yin, paapaa awon ololufe okunrin?
Biola: Mo sese n dide bo ni, mi o tii le so pe mo lawon ololufe bayii, sugbon to ba waye, ko si nkan ti mo fe e se bi won ba pe mi ju ki n da won lohun daadaa lo.

AWIKONKO: Ayeye ifilole fiimu tuntun ti e sese se yi, bawo lo se ri lara yin?
Biola: Inu mi dun gan an ni. Yoruba so pe beeyan ba n wa owo lo, to ba pade iyi lona, ko si nkan meji tiru eni bee tun fe e se ju ko pada sile lo. Ojo naa ye mi gidi, awon eeyan si gbaruku ti mi.

AWIKONKO: Fiimu yin di meloo bayii?
Biola: Fiimu akoko mi re o, 'Odaran Ife' lakole e. Ko ni pe e jade sori igba fawon ololufe mi lati je igbadun nitori awon eko to wa ninu e po jaburata.

AWIKONKO: Ki lo bi 'Odaran Ife'?
Biola: Olopaa ni eni to kopa (character) yen. Awon oga e nidi ise olopaa gbe ise kan le e lowo pe ko loo mu odaran kan to n gbe kokeeni wa fawon. O gba lati loo se e, sugbon nkan yi pada nigba to pade odaran yi. O bere sii nife odaran, ko wa si anfaani fun un lati sise ti won gbe le e lowo. Mi o fe e soro pupo, to ba jade sita, mo fe kawon eeyan loo ra a, ki won si farabale wo o.

AWIKONKO: Igba wo ni kawon eeyan maa reti e lori igba?
Biola: Ki osu keta ta a wa yi to o jale, o maa jade lagbara Olorun.

AWIKONKO: Ti a ba ni ka wo bi ayeye naa se lo si, a maa sakiyesi pe awon onitiata ko po nibi ifilole lojo naa. Nje eyi ko mu edun okan ba a yin?
Biola: Ko si edun okan to fe e mu ba mi nitori pe oju tuntun ni mi nidi ise tiata. Iwonba awon ti mo mo ni mo pe. Aimoye awon ti mo tun fiwe pe ti won ko wa, bi oro ayeye se ri ni yen, onikaluku lo ni ibi to fe e lo, nitori e ni ko se ba mi ninu je. Mo ti mo pe gbogbo eeyan ko lo maa wa, ida meta ninu awon ti mo pe lo wa nibe, ti inu mi si dun. To ba je pe awon oju lati Eko ati Ibadan le n reti, e o le ri won nitori pe oju tuntun ni mi.

AWIKONKO: Kinni kawon eeyan maa reti leyin fiimu yi?
Biola: Igbese to kan ni pe kawon eeyan maa reti igba ti fiimu naa yoo jade, ti idaniloju si wa pe lai pe, ninu osu yi, o maa jade sita.

AWIKONKO: Oro amonran yin fawon eeyan, paapaa awon to sese n dide bo?
Biola: Ise to da a ni ise tiata beeyan ba ni afojusun nidi e, to si mo ibi to n lo, ti kii se pe eeyan n se radarada. Amonran mi fawon to fe e darapo ni pe ki won wa owo lona ti won ba mo, mi o ni ki won lo gbegba asewo o, nitori pe ko seni to fe e ran enikan lowo, eeyan to ba mo ibi toun n lo nikan ko le ran ara e lowo. Maa tun fi asiko yi rawo ebe sawon ololufe e wa pe ki won ye e ra ayederu fiimu nigboro, nitori pe ayederu n sakoba fun wa pupo. Ki won lo maa ra ojulowo fiimu lawon ibi ti won ti n ta a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI