Ijoba Buhari Yoo Pa Ijoba Awarawa - Pasito Iyunade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 11, 2018

Ijoba Buhari Yoo Pa Ijoba Awarawa - Pasito Iyunade

Oludasile ijo Pentecostal Sanctuary Bible Ministry to wa niluu Ijebu-Ode, Wolii Sunday 'Dare Iyunade ti bu enu ate lu isejoba Aare Muhammadu Buhari, paapaa ijoba APC wi pe pelu iro ati etanje ni won fi gbajoba lowo ijoba Goodluck Jonathan lodun 2015, ti won yoo si pa isejoba awarawa patapata.

Wolii Iyunade
Wolii Iyunade soro yi lakoko to n bawon oniroyin soro nibi ipade to se pelu awon oniroyin ni olu-ijo naa to wa ni ojule kesan an, adugbo Araromi, Odo-Egbo, Ijebu-Ode losan oni fun ti ipalemo ayeye odun kejilelogun ti won da ijo naa sile.

Ojise Olorun naa so pe egbe oselu APC lo ogbon alumokoroyi lati fi tan awon omo orileede yi pelu awon ileri ati ireti ti won gbe le won lowo, to si je pe asan ati ofo ni gbogbo e da le lori.

Iyunade ni gbogbo awon ise gidi tijoba APC ba ni won yi baje, ti won si ti n wa oko Naijiria pada seyin, ati pe adura nikan lo le ko awon eeyan yo lowo ijoba amunileru won.

O ni opo igba ni Olorun ti fi han oun pe ijoba Buhari yoo pon awon omo Naijiria loju pelu iyan ati ebi, ti won yoo si mu idiwon ba igbe aye won, eyi ti yoo mu ki won maa gbe ninu ise ati osi.

Wolii naa tun tenumo on pe oun ke tantan lakoko ipolongo idibo yo koja pe kawon eeyan ma se gba awon ileri tegbe oselu APC fi n polongo gbo, nitori Olorun ti fi han oun pe ko si n kan rere ti won fe e mu wole wa sorileede yi fawon eeyan.

Bee lo ni awon odo orileede yi nikan lo lase lati le ijoba APC kuro bi won ba gba kaadi idibo alalope won, iyen PVC ki asiko idibo to o de. O lawon odo gan an ni ojo iwaju orileede yi, ti won gbodo dide lati ja fun eto won kuro lowo awon oludari amunisin ati amunileru.

O tun so pe pelu gbogbo bi won se so pe won n gba dukia ati obitibiti owo lowo awon ti won ni won kowoje, sibe ko tii si akosile lati foju awon ti won gbawon owo ati dukia naa lowo won, dipo bee, apapin ni won n se awon owo ati dukia naa laarin ara won.

Wolii Iyunade to so asotele nipa ibo odun 1993 ati 1999 so pe Olorun tun fi iran toun ri lodun 2014 han oun pe enikan n bo ti yoo gbajoba, ti yoo si mu ifaseyin ba opolopo nkan lorileede yii, paapaa, eni naa yoo tun fipa sejoba Naijiria.

O ni Olorun so foun pe Naijiria yoo pada si oko eru biru adari bee ba fi le gbajoba orileede yii. Bakan naa ni ojise Olorun naa tun ni lodun 2015 ti Olorun so foun pe ebi yoo wa lorileede yii, ti oro naa si fese mule titi dasiko ta a wa yii.

Wolii Iyunade ni ju gbogbo e lo, kawon omo orileede yi mo pe Olorun fun ra e yoo saworan sinima ailewotan (season film) nipa ipo ti orileede yi wa, ti yoo si jeri ara e gege bi Olorun Alagbara.

Nigba to n soro lori Guusu Iwo-Orun (Southwest) orileede yi, o ni bawon Yoruba ko ba sora won pelu ise ti won gbe le won lowo lasiko yii, won yoo jiya pelu iponju, to je pe awon ekun to ku ni won yoo je ere eto oro aje won.

Lakotan, Iyunade ro awon omo Naijiria lati kun fun adura losan ati loru pelu itoni Bibeli to so pe 'e maa gbadura lai sinmi', nitori pe adura ni kan lo le gba orileede yi sile kuro lowo ijoba amunisin ati amunileru.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI