OSELU BERE: ADEBUTU FUN ILU META NI ERO AMUNAWA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 6, 2018

OSELU BERE: ADEBUTU FUN ILU META NI ERO AMUNAWA

...Nnkan ti Gomina Amosun ko tii se fun wa ni - awon araalu

Bimbola Akinloye

Se ni idunnu subu lu ayo awon araalu Ajebo, Isiun ati Aseese nipinle Ogun nigba ti Onarebu to n soju ekun Remo Federal Constituency nile igbimo asoju-sofin niluu Abuja, Onarebu Oladipupo Adebutu loo sabewo si won, to si tun fun won ni ero amunawa, tiransifoma (transformer).


Ojo Sande to koja yi lawon araalu meteeta naa gbalejo Onarebu Adebutu to to je omo baba Ijebu, iyen Adebutu Keshington.

Gege bi a se gbo, ero amunawa naa ti agbara e je 500KVA ni ilu meteeta to wa nijoba ibile Obafemi Owode gba, won si ti wa ninu okunkun lati bii odun meedogun seyin.

AWIKONKO gbo pe, bo tile je pe awon ilu bii Ofada, Adigbe, Alaafia/Kobape ati Egbeda ni won ti koko je anfaani ero amunawa yi, sibe Onarebu Adebutu ko dawo duro lati maa se iranlowo fawon eeyan nipa nnkan to ba n je won niya.

Nigba to n dupe lowo Adebutu, Olu tiluu Ajebo, Oba Reuben Oluwole so pe ko je tuntun pe Onarebu naa mu awon eeyan yi kuro ninu okunkun biribiri, to si mu won wonu imole ayeraye nitori pe ko sese maa se e fawon eeyan.

Oba Oluwole ni ipa ti baba Onarebu naa, Adebutu Keshington to naa ni Onarebu Adebutu tele, ati pe ore araalu pelu alaanu mekunnu ni won, bee lo gboriyin fun Adebutu fun ise takuntakun to n se.


Onarebu Seye Sonuga to fi ero amunawa naa lele so pe ona lati je ki oju awon eeyan la sijoba APC, ati pe kawon eeyan fojunsile daadaa lati mo iru eni ti won yoo dibo fun lodun 2019.

Okan lara awkn araalu to ba wa soro lojo naa so pe nnkan ti Gomina Amosun ko tii se latigba to ti debe ni, tawon si ti ko orisirisi iwe sijoba, tawon ko ri esi gba.

Lara awon to tun wa nibi eto naa ni, Oloye  Sulaiman Ajepeaye akowe fun awon baale ti ko din ni 319 to wa ni Igbeyin; Oloye Ndoka Nma to je Ohaneze Ndigbo niluu Aseese; Oloye Muyideen Kukoyi to je Asoju Baale Isiun ati Arabinrin Omolara Martins to je Iyaloja Isiun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI