O TAN O: WON NI EGBE NAPPMED DI EGBE OSELU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 5, 2018

O TAN O: WON NI EGBE NAPPMED DI EGBE OSELU

Bi iroyin to n lo kaakiri orileede Naijiria lasiko yi nipa ipade ti egbe awon to n ta oogun lorileede yi se lai pe yi niluu Abeokuta tii se olu ilu ipinle Ogun ba fi le je otito, a je pe afaimo ki omi ma teyin wogbin won lenu latari bi won se so pe won fe e so ipade naa di ti oloselu.

Joel Odoh
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, egbe awon to n ta oogun, Nigeria Association of Patent and Proprietary Medicine Dealers (NAPPMED) ni won se eto oloodun won ti won maa n gbe kaakiri niluu Abeokuta, nibi ti won tun ti lo anfaani e lati gba Aare egbe won patapata, Omoba Joel Odoh lalejo.

AWIKONKO gbo pe se lawon kan ti won je oloselu laarin awon omo egbe naa, tawon ko wa lati ipinle Ogun fee lo anfaani eto naa lati fi se ipolongo enikan ti won loo fe e jade dupo aare orileede Naijiria, iyen Alaaji Sani Halliru, toun je Aare egbe naa nipinle Zamfara.

Gege bi a se gbo, won lawon omo egbe ti won wa lati ipinle Abuja, Edo, Ekiti, Eko ati Zamfara ni won ledi apo po pelu awon kan ninu egbe naa nipinle Ogun pe ki won se aso egbejoda lati fi se iwode ti won fee fi bere eto olodoodun naa.

Eka (Division) egbe NAPPMED la gbo pe mefa ni won je nipinle Ogun, awon naa ni; Egba Division, Ijebu Division, Ota Division, Remo Division, Sagamu Division ati Yewa Division. Egba Division ni won gbawon to ku lalejo.

Sani Halliru
Lara awon to gbe iroyin naa si wa leti, eni naa ta a foruko bo lasiri so pe bo tile je pe oun kii se omo naa, sugbon gbogbo nnkan to n sele ninu egbe naa loun mo bo se n lo.

Eni naa so pe “Emi kii se omo egbe NAPPMED rara, sugbon ko si nnkan to n lo ninu egbe yen ti mi o mo. Wahala nla kan lo sele ni papa isere MKO Abiola to wa ni Kuto lojo Wesde to koja, se lo dabi eni pe won mu oselu wo ipade ti won se lati fi ba tawon omo egbe NAPPMED je nipinle Ogun.

“Nnkan to sele ni pe, awon omo egbe naa kaakiri Naijiria ni won wa fun ipade yi, nitori pe se ni won maa n gbe kaakiri, sugbon awon Egba Division lo gbawon lalejo ipade ti won se koja. Se lawon kan fe e fi eto naa se ipolongo fun okunrin kan to fe e jade dupo Aare Naijiria lodun 2019.

“Ko seni to tii le so inu egbe oselu ti Alaaji (Sani Halliru) naa ti fe e jade dupo, sugbon won se aso egbejoda pe ki won wo o lati fi se ipolongo, bo tile je pe won ta aso naa ni, sugbon ko seni to mo pe aso ipolongo oselu ni won ta fawon ninu awon omo egbe yato sawon ti won ti gbabodi laarin won.

“Gbogbo won ni won dawo aso yi, sugbon nigba ti won ko aso fun won, awon aso naa ko pe iye ti won san owo e, bo tile je pe awon kan gba a, sugbon awon Egba Division fariga pe awon ko le gba a, ayafi to ba pe iye ti won san owo e. Eyi lo fa a ti won ko fi wo aso naa lojo iwode.

“Igba to di ojo iwode, ti gbogbo won pade ni papa isere MKO Abiola lawon Egba Division rii pe aso oselu ni won ta fawon, ti won ko si mo nipa e, eyi lo mu ki won yari patapata pe a fi kawon to wo aso naa bo kuro lorun ki won too bere nnkan ti won wa a se ni pato.

"Igba ti won ko tete bo aso naa kuro lorun lo mu kawon Egba Division fibinu kuro, lai bawon kopa ninu iwode lojo naa, tawon to ku si bere sii binu si won."

Gbogbo igbiyanju lati ba awon oloye egbe naa, paapaa Aare egbe tipinle Ogun lati fidi e mule lo ja si pabo, sugbon ta a pada ri okan lara awon alakoso Egba Division, Arabinrin Juliana Babatunde soro.

Bo tile je pe Obinrin naa ko koko fe e so asiri to wa nipa e fun wa, sugbon to pada so pe se lawon kan fe e fi eto naa se ti oselu, ti won si fe e fi koba awon lodo ijoba nitori pe awon kii se oloselu.

Babatunde so pe egbe NAPPMED kii se egbe oselu, ko si si nnkan to kan awon pelu oselu Naijiria nitori pe akoba nla ojo iwaju ni yoo je fun egbe ti ko ni nnkan se pelu oselu ba darapo mo oselu.

Obinrin naa tun je ko ye wa pe se ni won fi aso egbejoda ti won gba owo e lowo awon lu awon ni jibiti owo nitori pe aso ti won san owo e ko ni won ta fawon, aso oselu ni won loo se wa, tawon ko si gba a lowo won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI