LEYIN ODUN MEWAA: OGD ATI KASAMU PADE NILUU ABUJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 6, 2018

LEYIN ODUN MEWAA: OGD ATI KASAMU PADE NILUU ABUJA

...Leru ba n ba egbe oselu APC

Bolanle Adeyemo

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lokan awon omo egbe oselu APC lorileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun ko tii bale, lori bi Seneto Buruji Kashamu ati Otunba Gbenga Daniel tun se pada di ore timotimo.

Se ni idunnu subu lu ayo awon omo egbe PDP kaakiri orileede Naijiria, papaa nipinle Ogun nigba ti won gbo pe Seneto Buruji Kashamu ati Otunba Gbenga Daniel, OGD pade niluu Abuja lojo Tusde to koja yi.

Bo tile je pe iyalenu loro naa si n je fawon kan ninu egbe naa, paapaa awon to wa ninu egbe alatako, sugbon ohun kan soso to han daju ni pe alaafia ati isokan ti pada wonu egbe naa, to si see se kegbe PDP tun pada gbegba oroke ninu idibo odun 2019 to n bo lona.

Gege bi a se gbo, won ni ipade kan ni OGD loo se pelu igbakeji Aare teleri lorileede yi, iyen Jenera Atiku Abubakar to fe e jade dupo Aare lodun 2019 niluu Abuja fun ti ipalemo ipolongo idibo naa.

Awon to gbe iroyin naa si wa leti so pe bi Kashamu se gbo pe OGD ti wa niluu Abuja, lo ba a sare loo ba a lati kii ku oriire bi Atiku Abubakar se yan an gege bi alaga eto ipolongo idibo Aare fegbe oselu PDP.

Bi awon mejeeji se pade ara won, ni won sare di mo ara won, ti won tun bo ara won lowo, leyin lawon mejeeji wonu yara lo ti won si loo sepade fun bii wakati kan.

Bo tile je pe won ko so nnkan ti won loo so ninu yara, sugbon ta a pada gbo pe lori bi egbe oselu PDP yoo se pada di eyokan lorileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun ni, ati bi isokan, irepo ati alaafia yoo se pada wonu egbe naa, ti ko sin ii si ikunsinu mo laarin awon omo egbe.

 Be o ba gbagbe, o ti fe e le lodun mewaa bayii ti Gbenga Daniel ati Buruji Kashamu ko ti gba ti ara won, tawon mejeeji ko si fe e ri ara won soju, eyi gan an lo n da wahala sile ninu egbe, sugbon ni bayii, alaafia ti joba laarin awon mejeeji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI