O ma ṣe o! 'Expensive', gbajumọ Ọnọrebu l'Ondo ku lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 16, 2021

O ma ṣe o! 'Expensive', gbajumọ Ọnọrebu l'Ondo ku lojiji


Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ti fi ye wa pe gbajugbaja Ọnọrebu kan nipinlẹ Ondo, Ọnọrebu Adedayọ Ọmọlafẹ, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si 'Expensive' ti jade laye.
 
Agbegbe Akurẹ South/North ni Ọnọrebu Expensive n ṣoju fun nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
 
Ohun ta a gbọ ni pe nnkan bi aago meji oru oni, ọjọ Aje, Mọnde ni Ọnọrebu Expensive jade laye nile ẹ to n gbe niluu Abuja.
 
Nigba to n fidi iroyin ọhun mulẹ, akọwe ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Kennedy Peretei, sọ pe adanu nla niku naa jẹ fawọn ninu ẹgbẹ.
 
Odun 2019 ni wọn dibo yan Onọrebu Expensive lati lọ ṣoju agbegbe Akurẹ South/North. O si ti figba kan ri jẹ alaga ijọba ibilẹ labẹ iṣakoso Gomina Oluṣẹgun Agagu.
 
Egbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo, nigba tawọn naa n sọrọ sọ pe ẹdun ọkan nla niku Onọrebu Expensive jẹ fawọn, ati pe adanu nla gidi ni pẹlu, nitori pe awọn ko figba kankan ro o ri pe yoo ku.
 
Bẹẹ ni wọn ba awọn mọlẹbi rẹ kẹdun, ti wọn si gbadura pe ki Olọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI