Amosun ba Gomina Abiọdun kẹdun iku baba rẹ, ẹ gbọ ohun to tun ṣẹlẹ lẹyin rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 16, 2021

Amosun ba Gomina Abiọdun kẹdun iku baba rẹ, ẹ gbọ ohun to tun ṣẹlẹ lẹyin rẹ


Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti ba Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun kẹdun iku baba rẹ to doloogbe gbe laipẹ yii.

Ile Gomina Abiọdun to wa niluu Ipẹru-Rẹmọ ni Sẹnetọ Amosun to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Ogun Central nile igbimọ aṣofin agba lorilẹ-ede yii ti lọ ba a kẹdun, to si tọwọ bọwe ibanikẹdun.

AWIKONKO gbọ pe Gomina Abiọdun ko si nile lakooko ti Sẹnetọ Ibikunle Amosun lọ ki i, eyi ti ko jẹ ko duro.

Lara awọn to fiṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe Sẹnetọ Amosun n lọ si ibi ipade kan to ṣe pataki ni, eyi ti ko jẹ ko duro titi digba ti Gomina Abiọdun yoo fi pada de, lati le jọ ki ara wọn.

Wọn ni ko ma dabi ẹni pe oun ko yọju lati ba a kẹdun lo jẹ ko fi oko kan pa ẹyẹ meji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI