Ẹ woju iya arugbo to n ta oogun oloro jẹun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 16, 2021

Ẹ woju iya arugbo to n ta oogun oloro jẹun


Ileeṣẹ to n gbogun ti asilo oogun ati gbigbe egbogi oloro lorilẹ-ede yii, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ iya agbalagba, ẹni ọdun mẹtalelaadọta kan,
Nnadi Chinyere pẹlu egbogi oloro olowo iyebiye.

Papakọ ofurufu ti Muritala Mohammed to wa lagbegbe Ikẹja nipinlẹ Eko ni wọn sọ pe ọwọ awọn ti tẹ Chinyere lọjọ kẹa, oṣu yii, iyẹn lakooko to fẹ maa lọ si orilẹ-ede Italy.
 
Wọn ni ọgọrun egbogi oloro ti wọn n pe ni Heroin lawọn ka mọ ọn lọwọ lakooko ti aṣiri rẹ tu si wọn lọwọ.
 
Inu awọn ike ipara la gbọ pe Chinyere ko awọn egbogi oloro naa si, ki aṣiri ma ba a tu sita, lai mọ pe omi yoo pada tẹyin wọgbin lẹnu.
 
 
Agbẹnu ajọ NDLEA, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi lo sọrọ yii sita lọjọ Aiku, Sannde ana niluu Abuja sọ pe ọkọ ofurufu ti Qatar Airways ni Chinyere fẹẹ wọ lọ si Florentine, lorilẹ-ede Italy ki ọwọ tọ tẹ ẹ.
 
O lawọn ti n fọrọ wa lẹnu wo lati mọ awọn igbesẹ ti wọn yoo tun gbe ko to di pe foju rẹ ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI