O ma ṣe o! Ara san pa Abdulmalik, ọmọ ọdun marun-un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 1, 2023

O ma ṣe o! Ara san pa Abdulmalik, ọmọ ọdun marun-un


Niṣe ni ariwo ikunlẹ abiyamọ sọ lagbegbe kan ti wọn pe ni
Nasarawa Yanlemu, ijọba ibilẹ Bakori nipinlẹ Katsina, nigba ti wọn sọ pe niṣe ni Ara deede san pa ọmọ ọdun marun-un kan ti wọn pe ni Abdulmalik Junaidu.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni nnkan bi aago meje alẹ Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni iṣẹlẹ ọhun waye, to si ko ibẹrubojo sọkan awọn eeyan, paapaa awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn.

Baba ọmọ naa, Ọgbẹni Junaidu Gide, nigba to n sọrọ sọ pe ṣọọbu loun ti kuro ni garaaji, iyẹn lẹyin ti wọn kirun Maghrib tan. O loju ọna ni ojo ti ka oun mọ.
 
Ọkunrin naa loju ẹsẹ loun ti gba ile lọ, lati lọ wo awọn ọmọ oun. o ni boun ṣe dele ni iyawo oun ti sọ pe gbogbo wọn ti lọ si mọṣalaṣi.
 
“Ko tii ju iṣẹju diẹ lẹyin eyi ni eyi to jẹ ẹgbọn rẹ sare de, to si ni nnkan nla kọlu Abdulmalik nigba tawọn n bọ nile, o si ti ṣubu lulẹ soju ọna.
 
“Nigba ti a sare debẹ, a gbe e lọ si ọsibitu ijọba ti Funtua, nibẹ si ni wọn ti jẹ ko ye wa pe o ti ku.”
 
Baba naa lo ṣalaye pe niṣe ni ara ọmọ naa jona lati aya titi de isalẹ, to si ni nitori pe ilẹ ti ṣu ati ojo to tun n rọ, aarọ ọjọ keji tii ṣe Tusidee lawọn sinku rẹ nilana musulumi

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI