Wọn ti yọ ọlọpaa to fipa gba owo lọwọ araalu niṣẹ l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 1, 2023

Wọn ti yọ ọlọpaa to fipa gba owo lọwọ araalu niṣẹ l'Ekoo


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ti yọ Sgt. Ekpo Shimuyere, to n ṣiṣẹ l'ẹkun Ṣogunle niṣẹ lori ẹsun wi pe o fipa gba owo, ẹgbẹrun mejidinlọgọrun-un naira lọwọ araalu.

 
SP Benjamin Hundeyin, to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo lo fidi iroyin ọhun mulẹ l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii, to si ni ọga to wa lẹka ẹsun naa ti gba aṣọ lọrun Shimuyere.

Hundeyin sọ pe niṣe ni ọlọpaa gba foonu araalu, to si yọ owo naa ninu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un niara to wa lapo ile ifowopamọ rẹ, eyi to ni o ku diẹ kaato.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI