Ile-ẹjọ giga t'ipinlẹ Ondo, eyi to wa niluu Akurẹ ti ju Gbenga Akintọla to jẹ agbẹ niluu Ondo sẹwọn ọdun mọkanlelogun, lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan an.
Agbẹ naa to wa lati ijọba ibilẹ Ondo East ni wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ lori ẹsun marun-un ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu idigunjale.
Wọn ni Akintọla ati ẹnikan toun ti na papa bora ni wọn jọ ṣẹ ẹṣẹ ẹsun ti wọn fi kan an an laaarin oṣu kẹjọ si oṣu kẹwaa, ọdun 2021 lagbegbe Oke-Olifi to wa nitosi ikorita Itanla, niluu Ondo.
A gbọ pe niṣe lo digun ja ẹnikan ti wọn pe ni Chidinma, lole, ti wọn si gba foonu Itel ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ogun naira, ti wọn si tun gba aadoje naira to wa ninu baagi rẹ.
Bẹẹ ni wọn ja Rufus Rhoda lole foonu Techno ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun mẹfa aabọ, ati foonu Techno K-7 miran, ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun marundinlogoji, ti wọn si tun ja ẹgbẹrun mẹrin aabọ naira gba.
Yatọ eyi, wọn ni Akintọla tun digun ja Ayọdeji Oluwayẹmisi lole baagi rẹ ti foonu iPhone ti owo rẹ ko din ni ẹgbẹrun marundinlaadọta naira, ati ẹgbẹrun mẹta din nigba naira lọwọ rẹ. Ada ati awọn nnkan ija oloro miran ni wọn sọ pe Akintọla fi gba awọn nnkan wọnyi.
Agbefọba Alako Abdulahi, to tako Akintọla niwaju ile-ẹjọ sọ pe awọn ẹṣọ aabo Amọtẹkun lo rọwọ to ọkunrin naa, ti wọn si lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ lọjoọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2021.

Abdulahi lo jẹ ka mọ pe foonu mẹrin, ọkada kan, baagi kan ati apo owo kekere kan ni wọn gba lọwọ Akintọla lasiko t'awọn Amọtẹkun lọ fa a le ọlọpaa lọwọ.
O ni niṣe ni Akintọla sọ pe ẹnikan to n jẹ Sunday Igbo lo gbe baagi naa foun, toun ko si mọ ọn ri.
O ni niṣe ni Akintọla sọ pe ẹnikan to n jẹ Sunday Igbo lo gbe baagi naa foun, toun ko si mọ ọn ri.
Ṣugbọn nigba toun naa n sọrọ niwaju ile-ẹjọ, ọkan lara awọn ti Akintọla a lole, Rufus Rhoda ṣalaye pe oun ati Chidinma lawọn jọ n lọ lọjọ naa, to fi di pe Akintọla sare jade ninu igbo pẹlu aṣọ iboju ati ada lọwọ.
Onidajọ W. R. Ọlamide ninu idajọ rẹ sọ pe oun ju Akintọla sẹwọn ọdun meje lori ẹsun igbimọ papọ ati ẹwọn ọdun mọkanlelogun lori ẹsun idigunjale, to si ni yoo ṣe ẹwọn naa papọ mọra wọn ni.
No comments:
Post a Comment