ARUN KORONA GBE SANWO-OLU ṢANLẸ L'EKOO, L'AWỌN ARAALU BA DIDE ADURA GBIGBONA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 13, 2020

ARUN KORONA GBE SANWO-OLU ṢANLẸ L'EKOO, L'AWỌN ARAALU BA DIDE ADURA GBIGBONA


Gbogbo awọn ara ati olugbe ipinlẹ Eko ni wọn ti dide adura gbigbona bayii fun Gomina wọn, Babajide Sanwo-Olu lori  ajakalẹ arun korona to kọluu lojiji.
 
Kọmiṣanna fun eto ilera n'ipinlẹ Eko, Dọkita Akin Abayọmi lo kede sita lalẹ ana ti i ṣe Satide-Abamẹta pe Gomina Sanwo-Olu ti ko arun naa.
 
O ni ọjọ Fraide ijẹta ni Gomina Sanwo-Olu ko arun naa lẹyin ayẹwo ti wọn ṣe fun un, eyi to f'idi rẹ mulẹ, ati pe o ti wa n'ibi to ti n gba itọju ni IDH to wa ni Yaba.
 
Dọkita Abayọmi ni ko ni pẹ Gomina yoo fi bọ lọwọ arun naa pẹlu awọn itọju ti wọn n fun un nibẹ.
 
AWIKONKO gbọ pe bi iroyin naa ṣe jade sita l'awọn ọmọ Eko ti bẹrẹ aawẹ ati adura gbigbona fun GominaSanwo-Olu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI