Nicki Minaj dero atimọle ni Netherlands, wọn lo gbe egboogi oloro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 26, 2024

Nicki Minaj dero atimọle ni Netherlands, wọn lo gbe egboogi oloro


Gbajugbaja onkọrin ilẹ Amẹrika nni, Nicky Minaj lo ti dero atimọle ni papakọ ofurufu ti Amsterdam Schiphol lori ẹsun wi pe wọn fura sii pe o gbe egboogi oloro.

Ileeṣẹ iwe iroyin Ducth kan lo gbe iroyin ọhun sita lọjọ Satide, ana.

A gbọ pe gbajugbaja olorin naa n palẹmọ lati lọ ṣere fawọn ololufẹ rẹ nirọlẹ ọjọ naa, ṣugbọn to gbe awọn aworan soju opo rẹ nibi ti awọn alakoso eto aabo ti n fọrọ wa a lẹnu.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa fidi rẹ mulẹ fun akọroyin AFP pe lotitọ lawọn mu obinrin ẹni ọdun mọkanlelogoji kan to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika, ṣugbọn ti wọn ko darukọ rẹ.

Ninu ọrọ agbẹnusọ ọlọpaa, Robert Kapel, o ṣalaye pe;

“A ko tii mọ iru ẹni ti ẹni to wa lahamọ wa jẹ, ṣugbọn mo le fidi rẹ mulẹ pe a ti mu obinrin ẹni ọdun mọkanlelogoji kan to n gbiyanju lati gbe egboogi oloro kọja lọ si orileede miran.

“Ifọrọwanilẹnuwo ṣi n lọ lọwọ.”

Minaj, ninu ọrọ to kọ soju opo ‘X’ rẹ sọ pe awọn eleto aabo sọ pe awọn ba egboogi oloro ninu ẹru oun, to si ni eleto aabo oun lo nii.

“Ẹ fi sọkan wi pe niṣe ni wọn gbe baagi mi lai jẹ ki n mọ. Oṣiṣẹ eleto aabo mi ti sọ fun tẹlẹ wi pe oun loun ni ẹru naa.

“Ni bayii, wọn ni mo gbọdọ lọ fun iṣẹju marun-un lati gba ọrọ mi silẹ nipa oṣiṣẹ aabo mi fun ọlọpaa.

“Wọn n gbero lati da mi duro ni, ki wọn ba a le kọ iroyin ti ko dara nipa mi.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI