Ronaldo yoo ṣi wa pẹlu wa fun saa to n bọ - Al Nassr - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 2, 2024

Ronaldo yoo ṣi wa pẹlu wa fun saa to n bọ - Al Nassr


Alaṣẹ ẹgbẹ Al Nassr nilẹ Saudi Arabia, Guido Fienga ti sọ pe ogbontarigi agbabọọlu nni, Cristiano Ronaldo yoo ṣi wa pẹlu wọn fun saa to n bọ.

O ni ko nii ṣe bi ẹgbẹ agbabọọlu naa ṣe padanu idije saa 2023/24 to kọja yii.

Ipo keji ni ẹgbẹ agbabọọlu Al Nassr ṣe ninu idije naa pẹlu aami ayo mọkanla ti ẹgbẹ agbabọọlu Al-Hilal to ṣe ipo kinni fi n la wọn.

Bakan naa ni wọn tun padanu idije King's Cup sọwọ Al Hilal naa lọjọ Fraide to kọja.

Eyi si tunmọ si pe Ronaldo pari saa yii lai gba ife ẹyẹ kankan.

Bo tilẹ jẹ pe ẹdun ọkan nla lo jẹ fun Ronaldo nitori ife ẹyẹ ti ko ri gba fun ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, sibẹ ohun ayọ lo tun jẹ fun un lapa keji pẹlu bo ṣe jẹ pe oun ni agbabọọlu to min awọn julọ ni saa yii ninu idije ife ilẹ Saudi ti a mọ si Saudi Pro League.

Fienga nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe Ronaldo yoo ṣi wa pẹlu wọn fun saa to ọdun to n bọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI