Aye o! Wọn yinbọn fun gbajumọ olorin Fuji nibi to ti lọ kọrin l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 2, 2024

Aye o! Wọn yinbọn fun gbajumọ olorin Fuji nibi to ti lọ kọrin l'Abẹokuta


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ẹbẹ iranlọwọ ni gbajugbaja olorin Fuji nni, Bọlọmọpe Saheed Akangbe ti gbogbo eeyan mọ si Landoma n belẹbẹ fun.

Ko si nnkan meji ti ogo ọjọ ọla orin Fuji naa n bẹbẹ fun, bi ko ṣe ti ẹsẹ rẹ ti awọn kan yinbọn fun, eyi to si ti n da laamu.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ kẹsan, oṣu kẹfa, ọdun to kọja ni wọn yinbọn fun Landoma ladugbo Ajitadun to wa niluu Abẹokuta.

Ibi ti ọkunrin naa ti lọ kọrin la gbọ pe awọn janduku ti yinbọn fun un, ṣugbọn ti ori pada ko o yọ.

Awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn wa nibẹ nigba naa la gbọ pe wọn sare doola ẹmi rẹ, ko ma ba a ku.

Ọpọlọpọ ọta ibọn ni wọn yọ ninu ẹsẹ rẹ lọjọ naa, to si jẹ pe latigba naa ni ọkunrin yii ko ti le jade lọ kọrin mọ.

Ẹsẹ ọhun lo n fi ojoojumọ yọ Landoma lẹnu, ti awọn dokita si ti n sọ pe afaimọ ni ki wọn ma pada ge ẹsẹ ọhun bi wọn ko ba tete ṣiṣẹ abẹ fun un.

AWIKONKO gbọ pe awọn ile iwosan ti wọn ti yọ awọn ọta ibọn lọjọ naa lọhun ko yọ ọ tan, idi ree ti ẹsẹ naa fi n da laamu lojoojumọ.

Nigba to n ke gbajare lori ikanni ayelujara ti Facebook lonii, ọjọ Aiku, Bọlọmọpe Landoma Saidi sọ pe iranlọwọ loun n fẹ bayii lati le ṣiṣẹ abẹ ẹsẹ rẹ.

O bẹbẹ pe ki awọn ololufẹ oun ma jẹ koun ku togotogo, ati pe ẹgbẹrun lọna ọọrun le ni ogun (₦320,000) naira pere loun nilo lati fi ṣiṣẹ abẹ, ki wọn le yọ ọta ibọn to ku lẹsẹ oun.

Ninu ọrọ to kọ sita, Landoma ni:

Ẹbi Ọmọ ologo, gbogbo ẹyin ololufẹ mi nile, l'oko ati lẹyin odi, mo fi Ọlọrun bẹ yin lori ẹsẹ mi ti wọn yinbọn fun ni layipo Ajitadun niluu Abẹokuta lọjọ kẹsan, oṣu kẹfa.

Ẹsẹ yẹn, wọn ni ọta ibọn ṣi pọ nibẹ. Mo ṣẹṣẹ lọ ya aworan (Scan) ni lọjọ Wẹside to kọja yii ni. Ayẹwo ọhun si sọ pe ọta ibọn ṣi pọ nibẹ.

Ẹ jọwọ, ẹ ran mi lọwọ, emi ni ti yin ni tootọ. Ẹ ma jẹ ki wọn ge ẹsẹ mi ooo. Ẹ ran mi lọwọ. Ẹsẹ naa ti n da mi laamu gidi gan-an.

Mo fẹ ṣe ayẹwo ati iṣẹ abẹ, gbogbo owo ti mo si nilo jẹ ₦320,000, mo si ti ri ₦120,000 ninu ẹ. Ko si iranlọwọ kankan ayafi Ọlọrun ati ẹyin ololufẹ awa olorin.

Ẹ jọwọ, mo fi Ọlọrun bẹ yin nitori to ba di nla ju bayii lọ, awọn eeyan a sọ pe mi o sọrọ jade, ati pe niṣe ni mo bo ara rẹ, mi o si fẹẹ ku togotogo.

Ẹ ṣeun o. Ẹ wo ọla Jesu Kristi, Anọbi Muhammad ati ọla Ifa Ọrunmila mọ mi lara. Ẹ ko ni pade agbako lagbara Eledumare to ju gbogbo aye lọ.

Emi ni ọmọ yin, Landoma.

Account Number: 0127110911
Account Name: Bolomope Saheed Akangbe
Bank: GTBANK

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI