Gbogbo aye n sedaro Moji Olaiya osere tiata to ku silu Canada - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 18, 2017

Gbogbo aye n sedaro Moji Olaiya osere tiata to ku silu Canada

Kayeefi ni iku gbajumo osere tiata nni Mojisola Olaiya si n je fawon omo Naijiria paapaa awon ololufe e kaakiri agbaye bo se je pe leyin osu meji gbako to bimo tan ni olojo de, ti iku si muu lo.

Moji Olaiya
Gege bi AWIKONKO se rii gbo, ipalemo fiimu agbelewo e kan to fee jade, Iya Okomi to fee safihan e fawon eeyan ninu osu keje to m bo yi, ko too dipe o di agbelewo lo n se lowo.

AWIKONKO gbo pe Mojisola sese se ayeye ikomojade omo e tuntun tan ni Toronto lorileede Canada ni, to si n palemo lati safihan fiimu naa tawon agba osere bii Funsho Adeolu, Foluke Daramola atawon min in ti kopa ninu e faraye nilu Eko.

Ohun ti a gbo nipa iku e ni pe ale ana ojoru Wesde to je osu meji geerege to bimo e tuntun, ni won so pe aisan okan tawon oloyinbo n pe ni Cardiac Arrest gbemi e lojiji.

Osibitu kan ni Toronto lo dake si leyin tawon dokita ti da duro o ni lati se suuru lodo won nitori aisan to n yo lenu naa. Baba e, Victor ko tii ri owo ti won ni ki won lo mu wa san ko too dipe olojo de.

Bo tile je pe ironu ti iku awon agba osere meji Olumide Bakare ati Pasito Ajidara lo si wa lokan awon eeyan bayii, sugbon eleyi tun je kayeefi nigba tiroyin naa tun jade sita pe Moju Olaiya naa tun ti ku.

Ojo eti Fraide ojo ketadinlogun osu keta ni Moji Olaiya bimo ni nnkan bi aago mejo asale, leyin odun kan to pade oko e tuntun to fun un loyun. Ko fee bimo naa si Naijiria lo je ko gba Canada lo lati lo bii si.

Moji ati omo e
AWIKONKO gbo pe leyin odun mejidinlogun to bi omo e akoko, lo tun bi omo miran tuntun yi, to si je pe opolopo wahala lo se ninu yara agbebi ki omo naa too jade. Wahala to se ninu yara agbebi yi ni won so pe o fa aisan okan sii lara nitori ti won so pe iberu bi yoo se bimo naa lo gba okan e.

Bi e o ba gbagbe, odun 2008 ni Moji pade oko e akoko, iyen Okesola, sugbon igbeyawo naa ko pe ko too tuka nigba ti won lokunrin naa ko fi gbogbo ara gba omo ti Moji ti bi tele gege bi omo ti e, wahala yi lo tu won ka.

Mojisola to je omo gbajumo olorin takasufe nni, Victor Olaiya ni won bi lodun 1975, to si je pe odun mejilelogoji lojo ori e bayii.

Ko lonka lawon fiimu agbelewo ti osere tiata yi ti kopa ninu e, nigba to je pe fiimu olose-ose kan to je ti Wale Adenuga, iyen Super Story lodun 90s lo gbe Moji Olaiya jade sita faraye ko too fi gbogbo ara wonu fiimu Yoruba.


Lara awon fiimu oloyinbo ati ti Yoruba to ti kopa ninu e ni No Pain No Gain, Nkan Adun, Agunbaniro, Sade Blade, Omo Iya Meta Leyi atawon min in. O si ti gba orisirisi ami eye oserebinrin to dara julo.

Moji ati omo e apakeji
Gege bi okan lara awon ore Mojisola se so, o ni oun ati Moji si loro ni ko pe to si je nnkan to so nipe oun fee lo sorileede United States, sugbon ohun e ko dabi eni ti nnkan n se lasiko tawon jo soro.

Oludasile Best of Nollywood Awards, Seun Oloketuyi naa tun jeri si iku Moji lori Instagram.

Aheso to tun n lo nigboro bayii ni eyi ti won n so pe o seese ko je pe ilu Canada ni won maa sin Moji Olaiya si nitori ti won so pe o si ni iya to je agbalagba atipe nile Yoruba eewo ni ki obi foju ri oku omo e.

Gbogbo bi nnkan ba tun se n lo si ni AWIKONKO yoo tun maa mu wa fun un yin lati ka a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI