Lopin ọsẹ to kọja yii, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 ni awọn ara agbegbe idagbasoke Surulere Akingbala to wa nijọba ibilẹ Ọdẹda, ipinlẹ Ogun pawọpọ lati yan alaga ati igbimọ iṣakoso tuntun ti yoo tukọ agbegbe naa fun ọdun mẹrin gbako.
Igun meji ni awọn to dibo naa pin si, ti awọn igun mejeeji si ni ọpọ awọn alatilẹyin to gbaruku ti wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn kan jawe olubori lai ni alatako.
Nibi eto idibo alalaafia to waye naa, ni awọn araalu ti dibo yan Ọgbẹni Adeniji Adebayọ gẹgẹ bi alaga tuntun.
Eto idibo naa ti awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ogun ati ijọba ibilẹ Ọdẹda ṣakoso rẹ, eyi ti wọn ṣe ninu ile ijọsin Christ Mission Baptist Assembly, Dalekọ lo lọ nirọwọ irọsẹ nibi ti awọn aṣoju ijọba ati awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti peju.
Lati bi oṣu diẹ sẹyin la gbọ pe awọn ara agbegbe naa ti n palẹmọ lati yan alaga miran, lẹyin ti iṣakoso awọn to n tukọ naa tẹlẹ tan.
Igun meji ni awọn to dibo naa pin si, ti awọn igun mejeeji si ni ọpọ awọn alatilẹyin to gbaruku ti wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn kan jawe olubori lai ni alatako.
Ṣaaju asiko yii ni aṣoju ijọba ti rọ awọn igun mejeeji lati fi ifẹ han si ara wọn, bi idibo naa ba pari, to si ni ki wọn pawọpọ lati ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ, ki alaafia le jọba.
Ọgbẹni Adeniji Adebayọ lo jawe olubori pẹlu ibo mẹtalelaadọrun, nigba ti ẹnikeji rẹ, Ọgbẹni Ọlaogun Moses ṣe ipo keji pẹlu ibo mọkanlelọgọta.
Nigba to n fi idunnu rẹ han, alaga tuntun naa dupẹ gidigidi lọwọ awọn araalu, pẹlu bi wọn ṣe fimọ ṣọkan lati fi ibo gbe oun wọle.
Bẹẹ lo ṣeleri wi pe igba ọtun yoo wọnu ilu naa, pẹlu boun yoo ṣe ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe ifẹ, alaafia ati iṣọkan jọba.
Awọn yooku ti wọn tun dibo yan ni Ademọla Adediran to jẹ igbakeji alaga; Ọgbẹni Daṣọ Oluwafẹmi to jẹ akọwe; Ọgbẹni Adekunle Oluwaṣeyi to jẹ igbakeji akọwe; Ọgbẹni Olubọwale Gbenga John to jẹ akapo ati Ọgbẹni Babayẹmi Oluyẹmi to jẹ oluṣiro owo.
Awọn miran ni: Adekunle Adekọya to jẹ akọwe owo; Ọgbẹni Ọlayiwọla Ayọbami to jẹ agbẹnusọ; Arabinrin Oriọla Adedoyin to jẹ akọwe eto araalu; Ọgbẹni Ogunkọya Wọle to jẹ aṣoju ọdọ; Ọgbẹni Daniel Oluwafẹmi toun jẹ oludamọran lori ọrọ ofin ati alẹnulọrọ agba keji (Ex-Officio 2), Ọgbẹni Adetutu Isaac.
Aṣoju awọn obinrin, Arabinrin Fakọya Elizabeth; alabojuto eto araalu, Ọgbẹni Ṣorunkẹ Ọladipupọ ati Ọjọgbọn Adeyọyin Olukunle toun jẹ aṣoju agba akọkọ (Ex-Officio 1) ni wọn yan lai ni alatako.
No comments:
Post a Comment