Ijọba ipinlẹ Ogun gbe oṣuba kare fun Ileeṣẹ simẹnti Dangote lori owo ori sisan deedee - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 28, 2025

Ijọba ipinlẹ Ogun gbe oṣuba kare fun Ileeṣẹ simẹnti Dangote lori owo ori sisan deedee


Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun ti gbe oṣuba kare fun ileeṣẹ simẹnti Dangote to wa niluu Ibeṣe, ijọba ibilẹ Guusu Yewa lori ṣiṣe otitọ nipa owo ori sisan deedee.

Ẹka ileeṣẹ ijọba to n pawo wọle fun ipinlẹ naa, OGIRS lo fi ọrọ naa lede laipẹ yii, to si ṣapejuwe Ileeṣẹ naa gẹgẹ bi eyi to n san owo ori to pọ julọ nipinlẹ ọhun.

Nibi abẹwo ibanidọrẹ ti awọn alakoso ileeṣẹ OGIRS naa ṣe lọ si ileeṣẹ Dangote, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe iwuri nla ni ileeṣẹ Dangote jẹ fun ipinlẹ Ogun, ti wọn si ma fi n yangan nibikibi.

Abẹwo ọhun ti alakoso ori papa wọn, Arabinrin Oluwaṣeun Ọlajubẹ lewaju fun ni wọn ṣe lati fi ẹmi imoore han.

Ọlajubẹ sọ pe awọn alakoso ileeṣẹ simẹnti Dangote ti fi apẹẹrẹ rere lelẹ lẹka eto iṣuna ati ipawo wọle fun ipinlẹ Ogun.

O wa rọ ileeṣẹ naa lati ma ṣe rẹwẹsi ninu igbesẹ naa, to si ni ọna kan ṣoṣo to le mu ki ipinlẹ ni idagbasoke ati ilọsiwaju ni bi owo ori ba n wọle deedee.

Nigba to n sọrọ, alakoso ileeṣẹ Dangote niluu Ibeṣe, Ọgbẹni Ayyagari Subbaraidu, dupẹ gidigidi lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun pẹlu igbesẹ abẹwo naa.

Subbaraidu ni gẹgẹ bi aṣiwaju, awọn gbọdọ fi apẹẹrẹ rere lelẹ, ki wọn si maa wo awọn gẹgẹ awokọṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI