Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gbe igbimọ ti yoo ri sọrọ sisan owo oṣu ati ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ, to fi mọ owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ-fẹyinti.
Igbimọ meji ọtọọtọ la gbọ pe ijọba gbe kaẹ lati le dẹkun iwa ojusaaju tabi madaru ninu eto naa.
Bi ijọba ṣe yan igbimọ laaarin awọn aṣoju ijọba, bẹẹ ni wọn yan laaarin ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, lati le rii daju pe eto ọhun lọ bo ti yẹ.
Awọn igbimọ naa ni yoo ṣe iwadii awọn oṣiṣẹ-fẹyinti, lati mọ bi wọn ṣe n gba owo wọn si, latigba ti wọn ti fẹyinti.
Igbimọ ẹlẹni mẹjọ akọkọ, eyi ti oluṣiro owo agba jẹ alakoso rẹ, ni yoo ri sọrọ iwadii awọn ti ipinlẹ, nigba ti igbimọ keji ti oluṣiro owo agba nijọba ibilẹ yoo ri sọrọ owo awọn tijọba ibilẹ.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ileeṣẹ to n ri sọrọ eto iṣuna, Babatunde Toyin Abdulrasheed fi sita, o ṣapejuwe awọn ọmọ igbimọ naa gẹgẹ bi awọn akọwe agba ti wọn ti fẹyinti, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹyinti nilẹ Naijiria, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, TUC, ICAN, ANAN, ati awọn miran.

No comments:
Post a Comment