Oselu ni won fi yan Ooni Ife; Alaafin ju gbogbo oba lo – Oba Adeyemi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 20, 2017

Oselu ni won fi yan Ooni Ife; Alaafin ju gbogbo oba lo – Oba Adeyemi

Alaafin Oyo, Oba Dokita Lamidi Olayiwola Adeyemi III (CFR, JP LLD) ti so pe ko si oba naa nile Yoruba to ju Alaafin lo, bo tile je won bere ariyanjiyan yi ni nnkan bi odun metadinlogun seyin, sugbon sibee, ko soba to to bee lati jade si soo pe oun ga ju Alaafin lo.

Alaafin
AWIKONKO: Bawo le se le sapejuwo ajosepo yin pelu awon oba alaye to kun ile Yoruba?
ALAAFIN: O dan monran pupo. Sugbon ariyanjiyan ti wa lori ipo, iyen talo ga ju. Se e ri, oro yi, odun 20s lo bere. Ko si oba to le so pe oun ga ju Alaafin lo. Titi di asiko yi, ko si oba to to bee lati jade sita gbagba ko soru e jade lenu; eda oro ni won n lo. Ti eyikeyi ninu awon oba ba fee koju Alaafin, bale tabi awon oloye agba kan lo maa lo lati se e, sugbon Alaafin ti jade sita lati so pe oun gangan ni olori awon oba alade nile Yoruba, ko si seni to takoo.
Ti e ba loo wo akosile Sir Lugard nipa eto oselu lodun 1917, nibe lo si so bawon oba se ga si ni ariwa ati guusu orileede yi. Baba mi tabi baba-baba-mi ko si nibe lati gba Lord Lugard lamoran pe ko koo bee. Ti o ba so pe Johnson se ojusaaju fun Oyo, loo wo C. R. Neeving, to so pelu ase pe Alaafin ni olori gbogbo ob anile kaaro-o-jiire-bi. Lo ka nkan ti Johnson ko, ki o si mo awon nnkan to ko nipa Alaafin lodun 1881, to so pe Emi, Adeyemi kinni, Alaafin Oyo, Oba gbogbo ile Yoruba.
Ninu leta e si ilu Oyinbo, iyen awon Biritiko (British) lodun 1881, lakoko ogun ajijaagbara, o koo pe “Emi, Oba ile Yoruba?” Ko si ariyanjiyan lori eleyi. Mo ti pe won nija lori ariyanjiyan, ko da fun bii iseju mewaa, se ni won sa loo nigba ti won mo pe awon eri aridaju wa nibe. Enikan koo laipe yi pe Alake lo koko sakoso itedo akoko. Se eyin gbagbo pe Alake to te itedo akoko do lodun 1830?

AWIKONKO: Nje e gbagbo pe itan Yoruba bere lodun 1830?
ALAAFIN: Sagbua, okan lara awon oloye Alaafin ni Alake akoko nilu Abeokuta. E lo ka iwe itan, Egba ati awon agbegbe e, okan lara awon Ojogbon akotan, Ojogbon Saburi Biobaku ko, oju-iwe keedogun, o so pe agbegbe kan ti a ya soto laafin Alaafin ni Egba koko wa, bi Alaafin si se n lo ase lori Alake atawon oloye e kii saimo foloko.

E loo wo iwe owo osu awon oba todun 1938, akosile bi won se n gbowo osu nigba naa wa ninu aafin mi nibi. Ojo kerinla odun 1914 ni won gbe ekun Oyo kale labe ofin, ati Ife, ati Ijesa ni won si wa labe ekun Oyo. Sugbon ki isejoba le tubo kesejare, won pin ekun Oyo si meta, iyen ni Ekun Oyo, Ekun Ibadan ti Ekun Oyo ati Ekun Ife/Ijesa ti Oyo. Awon oba alaye nibe ni won pin ase olori fun.

Ni Ibadan, Olubadan ni olori ekun Ibadan, Ooni ni olori ekun Ife, Orangun ni olori ekun Ila, ti Owa si je olori awon Igbomina. Alaafin si ni olori gbogbo won, ni osuwon, Aremo to je omoba Alaafin ni olori ekun Oyo. Eka kootu ogun ni won si fun awon ekun ogun to wa, to si je pe Alaafin ko figba kan jokoo ri nibe.
Nigba ti wahala wa laarin Ife ati Ijesa, Sir John Macpherson lo be Alaafin lati ba won da si. Alaafin lo ran Are Ilugbohun ati Alapini atawon omo Oyomesi lati lo gba won sile. Aala ti Alaafin fi pin won ni Enuowa lo si wa titi doni.
Ko nii se pelu gbonmisi-omioto to wa laarin Ife ati Ede, ase ti Alaafin pa si n sise doni. Nigba ti wahala de laarin Ibadan ati Egba lori oro Bakasari, Alaafin lo yanju e to si so fun won pe Ibadan lo ni Bakasari, to si paa lase fawon mejeeji pe ki won towo bowe adehun pe wahala ko tun nii gberi mo lori e.

AWIKONKO: Ko soju abe niko, a gbo pe won pin Oyo atijo si meji, Oyo ati Osun nitori ija olori to wa laarin eyin ati Ooni Ife. Se looto ni?
ALAAFIN: Mi o mo igbese ti ijoba n gbe labele lori oro naa. Sugbon mo fe eyi fun un yin pe oselu lo fa ooni jade. Opo awon nkan ni a o le fowo bo mole ninu iforowero yi. Gege bi mo se so fun un yin, ibeere pe boya Alaafin lo ga ju laarin awon oba je ariyanjiyan ti ko tii odun mejidinlogun (20th Century) lo, nigba ti won yan Awolowo gege bi olori ekun Guusu atijo (old Western Region). Igba yen ni ijoba gbe oro Ooni jade, to si je pe ona kan soso ti won le fi se aseyori nigba naa ni ki won yanju Alaafin, eyi ti won se lati mu Alaafin bale, ti won si yan Ooni Adesoji Aderemi lojo kejo osu kejo odun 1960 gege bi gomina ekun Guusu. Oro yiyan gomina yi ni lati fi anfaani fun okunrin ti ko ni aafin.

Nigba ti won gbe igbimo awon oba alaye (Traditional Rulers’ Forum) dide nilu Abuja, won yepere awon oba ile Yoruba. Won fawon Emir siwaju, ti won si fi awon oba Yoruba pelu Ooni seyin. Nigba ti mo wole, mo beere pe aga temi da, won ro pe maa lo jokoo seyin, mo kan yo okan lara awon iwe ti won le mo aga legbe Sultan tilu Sokoto nibi ti mo jokoo si. Ninu iwe ofin ti Clifford ko lodun 1922, Oba meji je gege bi asoju orileede Naijiria nibi ipade igbimo asofin, iyen Sultan Sokoto ati Alaafin Oyo. Alaafin lo je asoju Guusu nipinle Ekoo. Leyin ti mo kuro nibe, ti mo dele, mo lo ko iwe ifesunkanni to lagbara si Jenera Jeremiah Useni, ti mo si tun fi ranse si Jenera Abacha. Abasha ranse pe mi, mo si so fun un pe ijoba lo titi, kii se tenikan. O gba oro naa yewo, o si gba nkan ti mo so. Alake ati Awujale ko se nkankan lati ja feto won, sugbon emi ja feto temi.

Nigba ti won pe wa sibi ipade kan nilu Abuja ki a si mu awon isongbe wa dani fun ile itura ti a maa de si. Awon Emir mu eeyan mejo-mejo dani, won wa fi yara meji sile fun emi. Mo ko gbogbo eru mi lo si ibi ti won pese sile fun Aare (Presidential suites). Ariwo ti won pa ni pe, kii se emi ni won seto ibe yen fun, mo je ko ye won pe, nnkan ti won se ko bojumu. Se e rii, gege bi Alaafin, o o gbodo beru nkankan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI