Mojeed to sa Sanusi l’ada lori dero kootu l’Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 20, 2017

Mojeed to sa Sanusi l’ada lori dero kootu l’Abeokuta

Beeyan ba wa ni kootu Majisireeti kan to fikale si Isabo nilu Abeokuta ipinle Ogun l’Ojobo Tosde to koja yi, yoo mo pe ko si ese ti ko ni ijiya labe ofin nigba ti won bere sii ka esun si odomokunrin Mojeed Sanusi lese pe o fee sekupa ore e nibi ti won ti n ja.

Mojeed omodun mokandinlogun ni won so pe oun ati okunrin kan ti won pe oruko e ni Mufutau Sikiru jo n fa wahala, sugbon ti won so pe se ni Mojeed loo yo ada to si fi sa Mufutau lori.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ojo ketala osu yi ni won so pe oro ti ko to nkan sele laarin Mojeed ati Mufutau ni nnkan bi aago mesan aabo ale ladugbo kan ti won pe ni Isale Jagun, Iberekodo nilu Abeokuta tawon eeyan si n la won.

Gbogbo bi won se ni won n la won lawon mejeeji ko gbo, ko pe e ni won ni Mojeed sare wole, ti won si ro pe oro naa ti pari sibe, sugbon iyalenu lo je nigba ti won ri ada lowo Mojeed, to si so pe afi koun gbemi Mufutau.

Awon agbaagba to wa nibe ni won sare di Mojeed mu pe ko ma daran, sugbon esu to gbee wo lale ojo naa, ko je ko ronu pe oro naa le gbe oun dogba dele ejo, lo ba sa Mufutau lada lori.

AWIKONKO gbo pe bi ada naa se ba Mufutau lori, se loo subu lule, to daku, ni wonba sare gbee lo si osibitu to wa nitosi fun itoju, nibi ti won so pe okunrin naa si wa titi di bi a ti n koroyin yi.

Lesekese ni won ti loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si loo mu Mojeed, ko too di pe won gbe was ile ejo. Agbejoro awon olopaa, Ogbeji Sunday Egbejiale so fun adajo ileejo pe ese ti Mojeed se tako iwe ofin odaran ipinle Ogun todun 2006, ati pe Mufutau si wa losibitu nibi to ti n gba itoju.

Onidajo naa, Arabinrin Oriyomi Sofowora nigba to n se idajo naa so pe oun ko tii le ejo naa, sugbon ki Mojeed sa egberun lona igba ati aadota (N250,000) pelu oniduro meji.

Sofowora so pe awon oniduro naa gbodo je iya Mojeed ati eeyan pataki ladugbo tabi ninu ebi Mojeed, o wa sun igbejo min in si ojo karun un osu keje.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI