Won ti fee yo Gomina egbe olorin juju l’Ogun ni tipatipa bayi o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 3, 2017

Won ti fee yo Gomina egbe olorin juju l’Ogun ni tipatipa bayi o

Pelu bi nnkan se n lo bayii, afaimo ki oro naa ma kangun sile ejo nitori ti won so pe Gomina egbe olorin juju iyen, Association of Juju Musician of Nigeria, AJUMN nipinle Ogun, Ogbeni Samuel Owolabi ko se fee gbe ipo naa sile.

Obey Fabiyi
Bo tile je ohun taa gbo ni pe okunrin kan ti won n pe ni Ayo Owolabi lo mu egbe naa ti awon agba ilumooka olorin bii Oloye Ebenezer Obey Fabiyi, Shina Peters, Wale Thompson atawon mi in wa sipinle Ogun, sugbon ti won so pe ko si ilosiwaju kankan to de ba egbe naa latigba ti won ti yan Samuel Owolabi tawon eeyan tun un pe ni Uncle Owo.

Titi di bi a ti n koroyin yi lokunrin naa ko tii yoju siwa lati wa a so tenu e lori awon esun ti won fi kan, nigba to je pe funra e lo pe wa pe akoroyin wa pe oro ko ri bee, ati pe oun n bo, sugbon to si n foni doni, fola dola.

AWIKONKO gbo pe gbogbo ere tokunrin naa n sa bayii ni lati ma le je ki won yo oun nipo naa, nitori awon oro ibanuje ti won ni won n so sii pe se lo kan n fi oruko egbe naa se gbajumo, to si fi n pawo sapo ara e.


Ohun taa gbo ni pe odun kan pere ti won fun Uncle Owo yi pe ko fi satunse awon isoro tegbe naa n dojuko ko ni pee pe nitori ti won so pe ko seni to mo pe egbe kan wa to n je egbe AJUMN fun awon olorin juju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI