Jamiu ati Oluwole to fee foruko Gomina Ambode lu jibiti so pe awon ko jebi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 24, 2017

Jamiu ati Oluwole to fee foruko Gomina Ambode lu jibiti so pe awon ko jebi

"E dakun, e se wa jeje, a ko jebi" loro ebe to n jade lenu awon adaran meji kan, Rilwan Jamiu ati Balogun Oyewole niwaju adajo ile ejo giga kan to fikale lagbegbe Ikeja nipinle Eko lojo Aje Monde to koja yii.

Bo tile je pe adajo naa, Onidajo Sedoten Ogunsanya ti so pe oun ko nii fi aaye sile lati je ki won gba oniduro awon mejeeji, ki awon olopaa si maa ko won lo si ogba elewon to wa ni kirikiri, sibe o ti sun idajo siwaju.

Gege b'AWIKONKO se gbo, jibiti wo aadota milionu (#50,000,000) naira ni won lawon mejeeji ti won fi orisi esun meta otooto kan fe e foruko Gomina Ambode lu lodun to koja, ko to o di pe asiri won tu sita.


Ohun ta a gbo ni pe, ateranse kan ni lawon Jamiu ati Oluwole fi ranse si Arabinrin Abimbola Umar to je akowe owo ipinle Eko lojo kewaa osu Keji odun to koja, iyen February 10, 2016 wi pe ko fi aadita milionu naira ranse si akanti enikan ni kiakia.


Atejise naa lo bayii wi pe "AG, ni kiakia fi owo aadota milionu naira ranse si akanti ileese Dayder Limited ti nomba e je 002806988 ti ile ifowopamo Keystone. A maa soro to ba ya. H. E."

Bi atejise naa se lo, la gbo pe o fi obinrin naa lara, nitori to mo pe bi Gomina Ambode ba fe e bere nkan, nise lo ma a pe oun, kii se wi pe o maa lo atejise, lesekese loun naa ti mu foonu e, to si pe Gomina Ambode lati mo boya looto lo je pe oun lo fi atejise naa ranse soun.


Iyalenu la gbo pe o je fun Arabinrin Abimbola nigba ti Gomina Ambode so fun un pe oun ko mo nkankan nipa atejise naa, ko si fi nomba to fi atejise naa sowo sii, ati nomba pelu oruko akanti naa sowo sawon otelemuye lati sewadi lori e.

AWIKONKO gbo pe lesekese lawon otelemuye ti rowo to awon mejeeji, ti won si jewo pe looto ni, ati pe ise esu ni, sibe nnkan ti won tun si niwaju adajo ni pe awon ko jebi awon esun ti won fi kan won.

Ojo metadinlogun osu kokanla la gbo pe Onidajo Ogunsanya sun ojo igbejo min in sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI