Bilionu oodunrun ataabo (345.42) ni eto isuna odun 2018 nipinle Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 21, 2017

Bilionu oodunrun ataabo (345.42) ni eto isuna odun 2018 nipinle Ogun

Ni bayii, gbogbo eto lo ti pari fun eto isuna odun 2018 nipinle Ogun pelu bi Gomina Ibikunle Amosun se ti gbe obitibiti owo oni bilionu lona oodunrun ataabo naira, iyen #345.42b lo siwaju awon omo ile igbimo asofin lati bu owo luu.

Bo tile je pe ida metadinlogota (57%) ni owo naa fi le si eto isuna todun 2017 to n pari lo yi, sugbon nkan ti a gbo ni pe ninu owo to n wole nipinle Ogun ati lodo ijoba apapo, iyen IGR ni won yoo ti yo owo naa.

AWIKONKO gbo pe eka eto Eko lo gba owo to poju ninu owo naa, nitori pe #79 bilionu naira ni owo ti won fe e na le eto Eko naa lori.

Ohun ta a tun gbo ni pe yato sawon ise to n lo lowo ti won yoo yo ninu owo naa fi pari, ko tun di awon akanse ise ti won tun fe e dawo le lowo, ti won yoo si se lase pari ki sa isejoba yi to o pari lodun 2019.

Gomina Amosun je ko di mimo pe Eto Ise Agbe naa ko ni gbeyin lati gbe laruge ninu eto isuna odun to n bo, ti won yoo si mu ni okunkundun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI