IYAALE ILE KU S’ILE ALE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 22, 2018

IYAALE ILE KU S’ILE ALE


"E saanu mi, akoba nla leleyi" loro ebe to n jade lenu gendekunrin eni odun mejidinlogbon (28)kan, Kelvin Michael ti won loo ba iyaale ile kan, Monsurat Idowu sun titi tiyen fi ku mo labe lojo Wesde ose to koja yi.

Kelvin
Bawon eeyan se n so pe nnkan ti oju Monsurat wa lo lo ri, bee lawon kan n so pe e o see se ko je pe oti to n je ki nkkan omokunrin dide daadaa, eyi ti Kelvin mu lo fa sababi iku Monsurat.

Gege ba a se gbo, osu to koja ni Kelvin ati Monsurat pade ninu moto lagbegbe Ketu, nibe ni won ti gba nomba ara won, to di pe won bere si ba ara won dore ikoko latigba naa.

Ojo Wesde to koja yi la gbo pe awon mejeeji fipade won si adugbo kan ni Ota, iyen ile ore Kelvin. Nibe ni won si ti ba ara lasepo karakara, ti wkn gbadun ars won daadaa.

Lojiji la gbo pe nnkan yi pada fun iyaale ile naa ti won lomo ogoji (40) odun ni, to si bere sii pariwo pe ooru n mu oun lati inu jade sita. Nigba ti won Kelvin rii pe agbara oun ko fe e ka mo, lo ba sare pinu lati gbe e lo osibitu ijoba, iyen jenera to wa ni Ota.

Inu moto la gbo pe Monsurat Idowu dake sii, nigba to maa gbe e sonu osibitu naa lawon dokita so fun un pe oku eeyan lo gbe wa, ati pe gbogbo bi won se n beere lowo e pe ki lo pa Monsurat ni ko ri oro gidi kan so.

Eyi gan an lo mu ki okan lara awon osise osibitu naa, Benjamin Okereke gba tesan olopaa to wa legbe osibitu naa lo lati loo foro naa to won leti, ki iku Monsurat ma ba a je akoba fun won losibitu naa.

Bawon olopaa se de osibitu naa, ti Kelvin ti foju kan won, la gbo pe o ti fe e dogbon ba ese e soro, sugbon tasiri e pada tuu, ti won si muu, nibe lo ti bere sii bebeb pe ki won saanu oun nitori pe akoba niku e je foun.

Won ni se ni Kelvin gege ba a se gbo n so pe oun ko mo Monsurat ri teletele, inu moto lawon ti jo soro ife ninu osu to koja, ati pe ojoojumo lo maa m pe oun lori foonu pe ojo won lawon yoo tun foju kan ara.

Eyi lo mu koun so fun un pe ko wa a ba oun nile toun n gbe, to si je pe ile ore oun kan loun muu lo, tawon si jo o bata won lasepo daadaa, sadede lo so pe oun ko mo bi ara se n se oun, idi ni yii toun fi n gbe e bo wa osibitu fun itoju lai mo pe o maa pada ku.

Ko pe ni wpn lawon olopaa pe oko Monsurat ti won ni moto lo n wa l'Eko, iyen Ogbeni Lamidi Idowu lati beere bo ya ara iyawo e ko ya tele, iyen lo je ki won mo pe ko si nnkan to se Monsurat ko yoo jade nile laaro ojo naa.

Won ni Lamidi so pe Monsurat ko dagbere pe oun fe e jade lo sibikan koun to o jade lo sibise lojo naa.

Sugbon sa a, agbenuso fawon olopaa, Abimbola Oyeyemi nigba to n fidi isele naa mule, o je ko di mi mo pe oga awon, iyen Ahmed Iliyasu ti pase pe ki iwadii tubo jinle sii nipa nnkan to fa iku Monsurat.

Bee lo ni ki won si fi Kelvin pamo si ogba won lodo awon to n ri si iwa odaran, iyen State Criminal Investigation and Intelligence Department to wa ni Eleweran digba ti otito oro yoo fi jade.


PÍN-IN KÁÀKIRI