Asise nla ni mo se pe egbe oselu PDP ko wole nipinle Eko lodun 2003 - Atiku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 5, 2018

Asise nla ni mo se pe egbe oselu PDP ko wole nipinle Eko lodun 2003 - Atiku

Awon agba bo, won ni eri okan se pataki, ohun teeyan ba n se, eri okan ni yoo maa je kaakiri, irufe nnkan bee lo sele si igbakeji aare lorileede yii tele, Atiku Abubakar, lojo Aje, Monde, ose yii, to fi toro aforiji lowo gbogbo omo egbe oselu PDP nipinle Eko pe ki won foriji oun lori asise toun se lati ma se je ki egbe naa wole nipinle naa lodun 2003.


O soro yii lakooko to n sabewo sawon omo egbe naa nipinle Eko, fun ti erongba e lati dije fun ipo aare labe egbe oselu naa ninu ibo to n bo lodun 2019. Gege bo se wi, o ni bo tile je pe aare orileede yii toun je igbakeji e, Oloye Olusegun Obasanjo pase foun pe koun ri i pe won gba gbogbo ile Yoruba fegbe oselu naa sugbon toun kuna.

O ni nnkan to si faa nigba naa ni ajosepo to danmoran to wa laarin oun ati Asiwaju Bola Ahmed Tinubu toun naa je gomina ipinle Eko lakooko naa. Gbogbo igba toun ba si n roo, loun naa maa n kabamo pe asise nla loun se, o si je okan lara nnkan to mu ifaseyin  ba orileede yii, ti won ko fi kuro loju kan.

O so pe o se ni laaanu pe opo awon ti won je ki egbe PDP rowo mu nile Yoruba lodun 2003 ni won ti gba akoso egbe lowo won, ti ko si ye ko ri bee.O wa be awon omo egbe naa pe ki won foriji oun lori nnkan toun se yii ati pe iru e ko nii sele mo.

Atiku  tun so siwaju pe nigba tawon gba ijoba  lodun 1999, gbogbo ile Yoruba lo je egbe oselu (Alliance for Democracy) lo n sakoso won. Nigba ti ibo mi in si n bo, oun so fun oga oun iyen Oloye Olusegun Obasanjo pe ko foun lase lati gba gbogbo ile Yoruba, o ni o si foun, Oun si se e ayafi ipinle Eko nikan ni ko bo sawon lowo nigba naa.

Idi to ni o fi ri bee ni pe oun ati Tinubu ti n bara won bo latinu egbe oselu SDP, PDM, nitori e loun se yonda Eko fun un nigba naa, bi ki i ba se bee ni o rorun foun lati gba Eko lowo e, amo ni bayii to ti je abamo foun nitori bi won tun ti se gba gbogbo ile Yoruba.

Okunrin naa wa so pe’ Mo be yin, ki e foriji mi, ki e si fun mi ni oore ofe mi.Ipinle Eko yoo sise papo pelu awon egbe oselu PDP yooku lati gbakoso’.

Leyin to ti se ipade po pelu awon agba ati oloye egbe naa tan ni ofiisi egbe naa, lo tun ba gbogbo awon omo egbe soro, nibi to ti toro fun iranlowo won lati satileyin fun un ki tikeeti lati dije naa lee te e lowo.

Lara awon to tele wa ni  Otunba Gbenga Daniel, to je oga agba isakoso iplongo fun Atiku ati Oloye Godsday Orubebe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI