ILEEWE GATEWAY ICT POLITEKINIIKI NIPINLE OGUN TI GBEREGEJIGE - DOKITA OYEYINKA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 22, 2018

ILEEWE GATEWAY ICT POLITEKINIIKI NIPINLE OGUN TI GBEREGEJIGE - DOKITA OYEYINKA

Okan lara awon ileewe imo ero igbalode to peregede daadaa pelu eko imo ijinle sayensi to si ni afojusun rere fawon akekoo-jade ni Gateway ICT Polytechnic to wa lagbegbe Saapade, nitosi Iperu-Remo, ipinle Ogun.


O ti le lodun mewaa ti won da ileewe gbogbonise timo-ero igbalode naa sile labe Gomina Gbenga Daniel. Akoko iru e nipinle Ogun ni ileewe naa je, to si je pe pupo ninu awon akekoo-jade won ni won peregede lati figagbaga pelu awon akegbe won lagbaye, paapaa nipa kiko awon eto imo ero, iyen Programming ti won n lo fun orisirisi ero komputa, to fi mo foonu.


To ba ti le lodun merin seyin ti eeyan ti wo inu ogba ileewe naa gbeyin, to si pada de be lasiko yi, ko da a, ko nii seni ti yoo royin fun iru eni bee pe ayipada rere ti wole to won nileewe naa, ti won si ti lo ogbon imo ero igbalode, iyen ICT lati fi mu idagbasoke alailegbe ba ileewe naa.


Lojo Wesde to koja yi, iyen kokandinlogun osu yi (September 19th, 2018) ni AWIKONKO sabewo sileewe naa lati wo awon idagbasoke to ti de ba won. Ka mu ti egan kuro, ileewe naa tayo ju awon akegbe re lorileede Naijiria, paapaa nile adulawo lo, pelu awon yara ikawe ati eka eto amuseya ti won tun sese pari kiko e lo.


Oga ileewe naa, Dokita Isaiah Kolawole Oyeyinka b'AWIKONKO soro lori awon ipele idagbasoke ati ilosiwaju alailegbe to ti de ba won, paapaa lasiko to fi wa gege bi oga agba nibe. Okunrin naa je ko di mi mo pe ogorun din ni egberun kan (900) lawon akekoo to wa nileewe gbogbonise ti imo ero igbalode naa nigba to gba opa ase lati tuko e, sugbon ni bayii, awon akekoo naa ti le ni egberun marun un.


Eka ikekoo to wa nibe tele gege ba a se gbo ko ju mesan an lo, sugbon ni bayii, o ti le ni ogun. Wonyi ni awon oro ti Dokita I. K Oyeyinka b'AWIKONKO so lasiko iforowero.


MO FERAN LATI JE ONIMO-ERO (ENJINIA) LATI KEKERE


Nigba ti mo wa ni kekere, mo feran lati je onimo-ero to n to nnkan, eyi ti a n pe ni Mechanical ni ede Oyinbo. Nigba ti mo de ileewe ni mo rii pe gbogbo nnkan n yato si bi mo se lero. Igba ti mo maa wole iwe giga, imo isiro, Mathematics ni mo fi wole, ti mo si se daadaa ju awon akegbe mi lo. Beeyan ba je onimo-isiro, paapaa lorileede yi, ise owo iru eni bee le ma yo pupo, nitori pe isiro yen lo maa dojuko. Awa la maa n ko awon Enjinia atawon eleto isuna (accountant) nigba ti won ba ni isoro, ko si eni to mo ise wa nita.


Igba to ya ni mo tun ni anfaani lati tesiwaju loo kekoo nipa imo-ero komputa (Computer Science), ibe ni Olorun ti gbe ise wa yo. Riro ni teniyan, sise wa lowo Olorun, nitori pe ipinu Olorun lo se koko ninu aye edaa. Bi mo se n to nnkan papo naa ni mo tun un n ko eto (programming). Asiko igba ti mo fi je adari ni Yabatech l'Eko lo fi gbe ise owo mi yo daadaa.


Gbogbo awon eto ori komputa ti a n lo nileewe wa, awa la ko won, lati ori eto tawon akekoo fi n san owo lori ero ayelujara (website) wa, de ori bi a se n seto idanwo fawon akekoo, eyi ti a fi n gba foomu atawon nnkan min in, awa la se won jade. Ko si nnkan ti e fe e se nibi, e ko le san owo fenikeni, ori eka ayelujara wa le ti maa san owo naa wole sapo wa.


AWON IBI TI MO TI SISE TELE ATI IWE-ERI TI MO NI
Mo sise ni Yaba College of Technology to wa l'Eko gege bi oluko. Mo ni iwe eri Dokita, iyen PH.D ninu eko imo sayensi ti komputa (Computer Science) ti mo gba nileewe ogbin, iyen FUNAAB niluu Abeokuta. Yunifasiti tiluu Eko ni mo ti ni iwe eri akoko ati ekeji. Emi ni adari eka eto bo se n lo lona igbalode (Centre for Information, Technology and Management) ni Yabatech ki n to o wa sibi. Mo n ko awon akekoo nipa imo ero komputa. Mo je okan lara awon omo egbe to mo nipa komputa (Fellow, Computer Society) ati bee bee lo. Mo sise olukoni ni Yunifasiti tiluu Eko (University of Lagos), mo tun sise ni Politekiniiki tiluu Eko (Lagos State Polytechnic). Die lara awon ibi ti mo ti sise atawon iwe eri ti mo ni re e.


NIGBA TI MO DE SILEEWE YII
Ogorun din legberun kan lawon akekoo ti mo ba, sugbon ni bayii, a ti le ni egberun marun. Nigba ti mo de, awon eka ikekoo ta a ni ko ju mesan an lo, sugbon ni bayii, o ti di metalelogun, ko si tii duro sibe.


AWON ADOJUKO WA
Lati ko ileeko giga, paapaa lorileede Naijiria kii se ere omode. Ko si iye owo tijoba le fun un yin, e si maa ni adojuko owo, nitori pe opo nnkan ni e maa nilo gege bi ohun amusagbara ati amusoro lati ko ileewe igbalode ti yoo figagbaga pelu awon akegbe e.


Ko sibi ti adojuko ko si, yala laarin agbegbe ilu ti a wa ni, tabi laarin awon akekoo, adojuko yoo wa sa a ni. Adojuko akoko ti mo koko ba pade nibi ni pe a ko ni awon akekoo to po nitori pe ko seni to mo ileewe yi, sugbon ni bayii, Olorun ti gbe wa leke adojuko yi, a ni awon akekoo daadaa, won si ti mo ileewe yi kaakiri bayii.


Isoro owo naa tun je adojuko ti mo tun ba pade, nitori pe nigba ti mo de, ogorun din ni egberun kan (900) lawon akekoo ti mo ba, bo tile je pe ijoba n fun wa lowo, sugbon ti owo naa ko to wa a na lati fi tun ileewe se, nigba to je pe ileewe yi ko tobi, idi ni yii ti won fi ko ileewe yi papo soju kan, ko le tobi daadaa, sugbon awon ilu ti a wa yi dide pe ko le see se, a ko le gba ile to tobi ju eyi ti a ti gba lo, sugbon Olorun gbakoso leyin-o-reyin.


OJO IWAJU AWON AKEKOO WA
Ilana ti wa ta a la kale. A wa ko fe ki awon akekoo wa se tan, ki won sese maa wa ise kaakiri. Nigba ti won ba maa fi lo odun meji si merin nibi, won gbodo ti di oga ara won. Bi a se n ko won ni imo iwe, bee la n ko won nise owo (Entrepreneur), a ni eka ikekoo nipa ise owo (Centre for Entrepreneurship), bi apeere, bi won se le tun foonu ati komputa se, bi won se le ko eto (programme). A fe e si eka ikekoo kan lai pe, nibe ni won ti ma maa ko nipa bi won se n ko awon eto ati ilana lori foonu, eyi ti a pe ni Mobile App Centre, nibi ti won a ti kekoo lorisirisi.


Fun apeere, bi ile ijosin ba fe e se eto kan, ori e ni won a ti se, ko da a, bi won ba fe e san idamewaa, ori e naa ni. Orisirisi igbese la n gbe lati rii pe awon omo wa da duro bi won ba kekoo jade nitori pe gbogbo wa la mo pe ko si ise nita mo lasiko yi, a si gbodo ran ara wa lowo. A ti ka itan nipa awon omo Naijiria to je pe won ti da duro, fun apeere eni to se foonu TECNO, omo Naijiria wa nibi ni, ko si ibi ti won ko ti n lo foonu naa bayii.


BI A SE N PA OWO W'OLE
Ijoba lo ni ileewe yii, won si n se daadaa fun wa, osoosu nijoba n fun wa lowo lati maa fi sakoso ileewe yi. Won tun n gba wa nimonran pe a ko gbodo ma a fi gbogbo igba duro de awon, nitori naa, a gbodo maa ronu awon ona ti a le gba lati maa pawo wole. A o kan le jokoo, ka fowo leran maa wo ijoba, ka si maa fi gbogbo igba maa reti owo ka too jeun, nitori pe omo to po nijoba bi.


Mo gbe osuba kare ati oriyin fun ijoba Gomina Ibikunle Amosun nitori pe won se daadaa fun wa, ti kii ba a se ti Gomina Amosun ni, e ko le ri awon ayipada ati idagbasoke ti e n ri yi, bi won se n ran wa lowo naa ni won je ki ori wa pe. Asiko igba ta a maa jokoo lati reti owo ijoba ti koja, gege bi lamonran won, ka ronu awon ona ta a le gba maa pawo wole.


YATO SI OWO ILEEWE AWON AKEKOO, AWON IBI TI A TUN TI N RI OWO
A ti n seto lati gba owo ijoba apapo ti won maa n fawon ileewe giga, iyen TETFUND, a si wa lori e, e si mo pe ileewe giga gbogbonise to wa nipinle Ogun po, idi ni yii ti owo naa ko se tii te wa lowo. Awon ibomin in naa wa ti a tun ti n nilo iranlowo, bi apeere, ajo NCC fun wa ni komputa alagbeka, iyen Laptop to fe e to ogorun lati maa fi se idanwo lodun bii meji seyin, ni bayii naa, won tun ti le sii, a ti ninero alagbeka to ti to eedegbeta (300).


A ni ileese ti a ti n se omi (Pure Water Factory), a tun ni ileese ti a ti n se bulooku ikole (Block Making Factory), a tun n gbiyanju pe ki eka ikekoo ise owo naa le je orisun ipawo wole fun wa. Bi mo se n ba a yin soro yi, a fe e bere eka eto ise ogbin igbalode (Agricultural Technology), ti awon akekoo wa yoo ti mo nipa ise ogbin igbalode bii Poultry Management, Fish Farming, Plantations atawon nnkan min in ti won n se layika wa, ti a si fe e ni oko igbalode fawon eto yii. A ni eka ileewe yi (Mini Campus) lagbegbe Aiyepe, nibe ni eto yi yoo ti maa lo. Owo yoo tun maa wole nibe.


ETO IGBANI-WOLE
Ona kan soso ti akekoo le fi wole sileewe wa ni JAMB, yato si awon to ti ni iwe eri ND tele.


OWO ILEEWE WA
Owo ileewe wa ko ga ni lara, ko seni ti ko le wa sileewe yi nitori pe ileewe ijoba ni, ko si ye ki owo ileewe ijoba gani lara. Ko si eni ti yoo tewo gba owo ileewe lowo yin, ori ero ayelujara ni won ti n san gbogbo owo ti won ba fe e san, ti won a si gba kaadi onte pe won san owo, iyen receipt.

PÍN-IN KÁÀKIRI