AYE O: N'IJOKO, WỌN GUN BABA TOYE N'IGO LORI NIBI AYẸYẸ ỌJỌ IBI ỌMỌ RẸ, BẸẸ NI WỌN TUN GUN AZEEZ PA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 27, 2019

AYE O: N'IJOKO, WỌN GUN BABA TOYE N'IGO LORI NIBI AYẸYẸ ỌJỌ IBI ỌMỌ RẸ, BẸẸ NI WỌN TUN GUN AZEEZ PA

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ọgba SARS to wa ni Magbọn niluu Abẹokuta lawọn ọdọmọkunrin mẹta ati baale ile kan ti wọn fẹsun kan pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọ, ati pe awọn ni wọn ṣekupa ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọ nni, Saibu Azeez.

Adugbo Oyedele, Abule Lẹmọdẹ n'Ijoko Ọta la gbọ pe ọwọ ọlọpaa ti wọn lakoooko ti wọn da wahala silẹ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi Oluwatoye to waye lopin ọsẹ to kọja.

A gbọ pe ni nnkan bi aago meji oru lasiko tawọn ọrẹ Oluwatoye n ṣe faaji wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa de, ti wọn si bẹrẹ sii ko iya fawọn eeyan, ta a si gbọ pe Azeez ti wọn pa lawọn eeyan naa wa wa sibẹ.

Ọpẹyẹmi Ọlalekan, Azeez Ologundudu, Emmanuel Ọmọboriowo ati Anigilaje Babatunde lawọn ti wọn fẹsun naa kan.

AWIKONKO gbọ pe bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yi ṣe de ni wọn ti bẹrẹ sii pa igo mọlẹ mọlẹ, tọrọ si di boolọ o yago fawọn to wa nibẹ, a gbọ pe Baba Oluwatoyin gbiyanju lati parọwa sawọn eeyan naa, ṣugbọn kaka ki wọn gbọ, ṣe ni wọn gun baba naa nigo lori.

Bi wọn ṣe foju kan Azeez ti wọn sọ pe wọn wa lọ sibẹ, ni wọn ti da afọku igo bo o, ti wọn si gun un pa. Asiko ti wahala naa n ṣẹlẹ la gbọ pe awọn to wa nibẹ ti ranṣẹ sawọn ọlọpaa, ṣugbọn ki wọn too de, Azeez ti jade laye.

Lẹyin o rẹyin la gbọ pe wọn rọwọ to awọn mẹrẹẹrin naa, ti wọn si n gbatẹgun alaafia lọgba SARS dasiko yi. Bẹẹ ni Kọmiṣana ọlọpaa ti sọ pe awọn eeyan naa yoo foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI