ỌDAJU ABIYAMỌ ṢEKU PA AWỌN ỌMỌ RẸ MẸTA, LO BA NA PAPA BORA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 18, 2019

ỌDAJU ABIYAMỌ ṢEKU PA AWỌN ỌMỌ RẸ MẸTA, LO BA NA PAPA BORA

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan ni ko tii sẹni to le sọ ibi ti iyaale ile kan ti wọn loo ṣeku pa awọn ọmọ rẹ mẹta salo, lẹyin to huwa buruku naa tan.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Awo Idemili to wa nipinlẹ Imo la gbọ pe iṣẹlẹ kayeefi naa ti waye lọjọ Ẹti (Furaide) ọsẹ to kọja yi nigba ti wọn loo tan ọkọ rẹ, Emeka Ajoihe lọ si iṣọ-oru.

 
Ohun ti a gbọ ni pe ṣe ni obinrin naa ti a ko tii mọ orukọ rẹ dasiko ta a fi ko iroyin yin jọfọgbọn tan ọkọ rẹ wipe ko lọ si iṣọ-oru ti wọn ṣe ni ṣọọṣi wọn lalẹ ọjọ naa, laimọ wipe ero buruku ti wa ninu ẹ to fẹẹ ṣe.

Wọn ni ọkọ rẹ, Emeka ṣe jade nile, lo ki awọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta mọlẹ, to si lu wọn pa. Nigba ti ọkọ rẹ yoo fi pada de ile laarọ ọjọ keji, iyalẹnu ni wọn loo jẹ wipe oku awọn ọmọ rẹ lo ba nilẹ.

 
Ọmọ oṣu marun un si mẹfa, ọmọdun meji ati ọmọdun mẹta lawọn ọmọ naa ti wọn loo pa danu, ta a si gbọ pe iwadii awọn ọlọpaa ti bẹrẹ lati mu iyaale ile naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI