ÀWỌN ADIGUNJALE YINBỌN PA ỌKỌ̀ OLÓYÚN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 23, 2020

ÀWỌN ADIGUNJALE YINBỌN PA ỌKỌ̀ OLÓYÚN


Iroyin kan tí kò fi bẹẹ dùn mọ àwọn èèyàn nínú tó tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yìí ni pé àwọn adigunjale tí wọn kò tíì mọ yinbọn pá gbajugbaja oníṣòwò kan nílùú Eko, Alaaji Fatai Yussuf tọpọ àwọn èèyàn mọ sì Ọkọ̀ Oloyun.

Ọsan òní là gbọ pé àwọn adigunjale náà yinbọn pá ọkùnrin náà lójú ọ̀nà Abẹ́òkúta silu Isẹyin.

Alaaji Fatai ni olórí àwọn tó ń ṣe oogun lorilẹ-ede Naijiria kò tóò kú.  Ohun tí ọkàn lára àwọn tó tún sunmọ Ọkọ̀ Oloyun ṣàlàyé F'AWIKONKO ni pé lóòótọ́ ni wọn yinbọn fún Ọkọ Oloyun, ṣùgbọ́n kò kú, tó sì ni ẹsẹ kan ayé, ẹsẹ kan ọrùn lo wá di àsìkò tá a fi kọ ìròyìn yìí tán. 

Ẹkùnrẹrẹ ìròyìn náà ń bọ̀ laipẹ 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI