Ẹ WO ILU TI WỌN KII BU OMI S'ARA, ṢUGBỌN GBOGBO AWỌN OBINRIN WỌN LO R'ẸWA PUPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 30, 2020

Ẹ WO ILU TI WỌN KII BU OMI S'ARA, ṢUGBỌN GBOGBO AWỌN OBINRIN WỌN LO R'ẸWA PUPỌ

Bi wọn ba n sọ nipa awọn ilu ti wọn ṣi n gbe igbe aye atijọ, ko da, ti oju wọn ko ti i la rara, ilu kan l'orilẹ-ede Namibia, ilẹ Afrika ni.

Wọn ki i bu omi s'ara rara, bẹẹ si ni gbogbo awọn obinrin wọn r'ẹwa pupọ pẹlu awọn nnkan ti Ọlọrun fi jinki wọn. Ki i ṣe pe o wu wọn lati ma maa bu omi s'ara, ṣugbọn nitori aisi omi nitosi la gbọ pe o fa a ti wọn ki fi i wẹ.

Himba l'orukọ ilu naa n jẹ, apa Kenene lo wa l'orilẹ-ede Namibia. Aṣa ati iṣe wọn ṣi wa sibẹ l'atigba ti wọn ilu naa ti wa, ti ko si yipada l'atigba naa titi di asiko yii.

Ohun kan to tun n je kayeefi ninu ilu yii ni pe ọfẹ l'awọn obinrin maa n fun awọn alejo wọn ni ibalopọ, eyi to yatọ patapata si awọn ilu to ti dagbasoke daadaa.

Awọn araalu Himba n da gbe nigbe aye to rọ wọn l'ọrun, ti wọn si jinna rere s'awọn to le da nnkan ru fun wọn l'ojiji. Alejo to ba lọ sibẹ ko nilo lati ṣẹṣẹ maa bẹbẹ lati ri ẹni ti yoo ba lopọ, gbogbo ẹni to ba k'ọnu si ni yoo gba fun un.

Bẹẹ ni wọn ko ri iwa ikobinrin jọ gẹgẹ bi ohun to buru, nitori pe igbe aye ti wọn n gbe n tẹ wọn l'ọrun. Awọn oriṣa atijọ l'awọn eeyan yii ṣi n f'oribalẹ fun titi d'asiko yii.

Idi kan pataki ti wọn ki i tun ṣe kundun lati maa wẹ ni bi oju wọn ṣe ri, awọn ipaara wọn tẹ wọn l'ọrun lati maa lo, eyi lo si maa n jẹ ki wọn maa dan.

AWIKONKO gbọ pe awọn eeyan yii maa n lo agbo (herbs), ti wọn yoo si gbe le ina eedu, ori ẹ ni wọn yoo jokoo le, ti yoo si jẹ ki wọn laagun, aagun naa ni wọn fi n ṣan ara wọn.

Bakan naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ki i fẹ k'ẹnikẹni da si ọrọ aṣa ati iṣe wọn, sibẹ, wọn fẹran awọn alejo pupọ. Bi ẹyin naa ba n'ifẹ lati ṣ'abẹwo si ilu yii, ẹ le tẹkọ leti lọ sibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI