IDI TI WỌN ṢE FẸẸ RAN MI L'ẸWỌN - RUNṢEWE PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 10, 2020

IDI TI WỌN ṢE FẸẸ RAN MI L'ẸWỌN - RUNṢEWE PARIWO SITA


Laipẹ yi n'ile ẹjọ giga to f'ikalẹ siluu Abuja paṣẹ wi pe ki wọn ju Alakoso Agba fun ajọ to n ri sọrọ eto Aṣa ati Iṣẹṣe, The National Council For Art and Culture, iyẹn Ọtunba Ṣẹgun Runṣewe s'ẹwọn d'igba ti wọn yoo fi rii lati wa a sọ t'ẹnu ẹ lori bi wọn ṣe ti Abule Aṣa ati eto idagbasoke iṣẹ ọwọ t'ibilẹ, eyi ti owo ẹ fi diẹ din ni biliọnu mẹwaa (9.8) naira, ti wọn si l'awọn agbanipa ti sọ ibẹ di ile.

Ọkunrin naa ti wa a sọrọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an wi pe ko si nnkan meji to jẹ ki wọn fẹẹ ba t'oun jẹ bi ko ṣe pe oun da awọn alajẹbanu l'ohun, toun ko si fun wọn ni nnkan ti wọn n fẹ.

Ọjọ kẹẹdogun oṣu kejila ọdun 2017 ni ile ẹjọ ti paa laṣẹ pe ki ọtunba Runṣewe yọju lati wa a tako awọn ẹsun ti wọn fi kan an, ṣugbọn ti wọn ni ko yọju, eyi lo mu ki Onidajọ to n gbọ ẹjọ naa fi paṣẹ wi pe ki wọn lọọ ju ọkunrin naa s'ẹwọn fun bo ṣe tapa si ofin ile ẹjọ.

Runṣewe nigba to n d'ahun si awọn atẹjiṣẹ, ipe ori aago t'awọn ololufẹ rẹ n fi ranṣẹ, o ni ọwọ Ọlọrun ni ẹmi oun wa lasiko yii.

Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe oun yoo sa gbogbo ipa ati agbara oun lati rii pe oun mojuto gbogbo awọn nnkan eto iṣẹṣe to jẹ orilẹ-ede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI