ORIIRE NLA: IYANUOLUWA, ỌMỌ OLUKỌ AGBA FCE ABẸOKUTA K'ẸKỌỌ GB'OYE NI FASITI FUNAAB - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉWednesday, January 29, 2020

ORIIRE NLA: IYANUOLUWA, ỌMỌ OLUKỌ AGBA FCE ABẸOKUTA K'ẸKỌỌ GB'OYE NI FASITI FUNAAB

Ko si adura meji ti gbogbo awọn abiyamọ toootọ aye maa n gba bi ko ṣe pe k’awọn jeere ọmọ wọn, ti wọn yoo si duro ti iru ọmọ ti wọn ba fẹ jeere rẹ digbidigbi.

Wọn yii gan an l’ọrọ to lọ n’ibamu pẹlu b’awọn eeyan kaakiri agbaye ṣe n ba Olukọ Agba Ede Yoruba nile Ẹkọ awọn Olukọni Agba t’ijọba apapọ (Chief Lecturer, Federal College of Education), eyi to fikalẹ si Oṣiẹlẹ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, iyẹn Ọmọwe Aderẹmi Olusọji Fajẹnyọ yọ lori bi ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Iyanuoluwa Fanjẹyọ ṣe kẹkọọ-gboye ni ile ẹkọ giga ti Ọgbin nilu Abẹokuta, iyẹn Federal University of Agriculture (FUNAAB).

Image may contain: Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, standing 
Ọjọ Iṣẹgun Tusidee anaa ni eto ikẹkọọ-gboye naa ti waye ni Fasiti Ọgbin, iyẹn FUNAAB naa nilu Abẹokuta, nibi t’awọn akẹkọọ ti ko din ni ẹgbẹrun kan ti kẹkọọ jade.

Lara awọn to kẹkọọ jade naa ni Iyanuoluwa fajẹnyọ, to jẹ ọmọ Olukọ Agba ti FCE, Oṣiẹlẹ Abẹokuta yii, to si jẹ pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ṣi n ba idile Fajẹnyọ dunnu lori bi ọmọ wọn ṣe ṣe aṣeyọri.

Image may contain: 1 person, smiling, standing and outdoor 
Ẹka ikẹkọọ n’ipa awọn ẹranko, iyẹn Animal Science la gbọ pe Iyanuoluwa ti kẹkọọ jade, ti wọn si looo pẹlu awọn to gbajumọ daadaa l’ẹka ikẹkọọ naa lori bo ṣe n tayọ ninu ẹkọ rẹ.

Image may contain: 2 people, people standing, sky and outdoor
Iyanuoluwa
B’awọn mọlẹbi ati ololufẹ gbajugba olukọ t’ọpọ awọn eeyan n tọ ipasẹ rẹ yọ, ni gbogbo awa alaṣẹ ati oṣiṣẹ ileeṣẹ IROYIN AWIKONKO naa la n ba idile Fajẹnyọ yọ, ti a si n gba a l’adura pe ọmọ naa yoo tubọ ṣe aṣeyọri ti ko l’ẹgbẹ l’aye.

Bakan naa la tun n gba a l’adura pe baba naa yoo jẹun ọmọ pẹẹpẹẹpẹẹ lagbara Ọlọrun to da aye ati ọrun, ti ounjẹ ọmọ naa ko si nii koro l’ẹnu rẹ.

Diẹ tun re e l'ara awọn fọto ayẹyẹ naa:
Image may contain: 5 people, including Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, people smiling, people standing, wedding, beard and outdoor

Image may contain: 2 people, including Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, people smiling, people standing


Image may contain: 3 people, including Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, people smiling, people standing

Image may contain: 3 people, including Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, people smiling, closeup


Image may contain: Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, smiling, standing


Image may contain: 3 people, including Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, people standing


Image may contain: 2 people, people smiling, people standing


Image may contain: 2 people, including Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, people smiling, people standing and suit


Image may contain: 2 people, hat


Image may contain: 3 people, people smiling, people standing and crowd


Image may contain: 3 people, including Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, people smiling, closeup


Image may contain: Prince Iyanu Fajenyo-Atobatele, smiling, closeup1 comment:PÍN-IN KÁÀKIRI