WỌN DA ẸJỌ IKU FUN JAMIU ATI GANIU L'EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, January 24, 2020

WỌN DA ẸJỌ IKU FUN JAMIU ATI GANIU L'EKITI

Ile-ẹjọ Giga to f'ikalẹ siluu Ado Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yegi fun awọn ọdọmọkunrin meji kan, Jamiu Idris ati Ganiu Issah lori ẹsun idigunjale t'awọn ọlọpaa fi kan wọn.

Ẹsun meji ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu iwa idigunjale la gbọ pe wọn fi kan Jamiu ati Ganiu, ti ile-ẹjọ si paṣẹ pe wọn jẹbi awọn ẹsun naa l'Ọjọbọ Tọside ana.

 Ibọn pẹlu ada la gbọ pe awọn ọrẹ meji fi n jale, ti wọn si n p'awọn eeyan l'ẹkun jaye. Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ọbanibi Adams l'awọn mejeeji fi ibọn gba mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry ti nọmba idanimọ ẹ jẹ LND 118 EA lọwọ l'adugbo D5 Progress, Poly Road, Ado Ekiti.

Ohun to n jẹ kayeefi ni pe oṣiṣẹ l'awọn mejeeji yii jẹ fun Ọgbẹni Adams, ko too di pe wọn pamọ pọ lati ja a l'ole.

Bo tilẹ jẹ pe awọn mejeeji sọ pe awọn ko jẹbi, ti wọn si bẹbẹ fun aanu, sibẹ Onidajọ John Adeyẹye sọ pe wọn yoo lọ maa tọrọ idariji l'ọrun, l'ẹyin ti wọn ba yẹgi fun wọn tan.

1 comment:PÍN-IN KÁÀKIRI