WỌN DANA SUN BAALE ILE TO YINBỌN PA IYAWO RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉWednesday, January 29, 2020

WỌN DANA SUN BAALE ILE TO YINBỌN PA IYAWO RẸ

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi agbegbe t'iṣẹlẹ naa ti waye mulẹ titi d'asiko ta a ṣ'akojọpọ iroyin yii tan, ṣugbọn kayeefi lọrọ naa ṣi n jẹ fun gbogbo awọn to gbọ patapata, ti wọn si n ṣepe fun baale ile naa lọna ọrun. 

Image may contain: fire and outdoor 
A gbọ pe o ti pẹ ti baale ile naa ti maa n lu iyawo rẹ,ti wọn si ni kii dun mọ awọn ara agbegbe ti wọn n gbe ninu. Wọn ni ọpọ iya ni baale ile naa fi n jẹ iyawo to bi ọmọ mẹrin fun un.

Image may contain: 1 person, on stage, standing and outdoor 
Wọn ni ẹkọ ati akara ni iyaale ile naa fi n bọ ara rẹ, ti ko si s'ẹni to ko mọ-ọn ni gbogbo agbegbe naa.

Image may contain: one or more people, people standing and outdoor 
Ṣadede la gbọ pe baale ile naa yọ ibọn, to si yin in pa iyawo rẹ. Loju ẹsẹ la gbọ pe awọn araalu ti wọn wa n'itosi ti pe le ọkunrin naa lori, ti wọn si dana sun un loju ẹsẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI