WỌN JU IYA ATI ỌMỌ RẸ S'ẸWỌN ỌDUN MEJILA GBAKO L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 29, 2020

WỌN JU IYA ATI ỌMỌ RẸ S'ẸWỌN ỌDUN MEJILA GBAKO L'EKOO

Ile-ẹjọ giga apapọ to f'ikalẹ silu Eko ti ju Arabinrin Damilọla Ahmed Adeyẹri ati ọmọ rẹ, Alaba Kareem Adeyẹri s'ẹwọn ọdun mejila pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun jibiti owo ti wọn ni ko din ni ẹgbẹrun mejilelọgọrin dọla ($82,572).

Ọmọ ilu Oyinbo kan la gbọ pe Damilọla ati ọmọ rẹ lu ni jibiti owo yii, ko too di pe aṣiri wọn pada tu l'ọjọ kẹfa oṣu kẹsan an ọdun to kọja.
 
AWIKONKO gbọ pe  oṣu kẹfa ọdun 2017 l'awọn mejeeji lu jibiti naa, n'igba ti wọn lẹdi apo pọ pẹlu ọkunrin kan ti wọn e orukọ ẹ ni Kareem Rusell t'oun ti na papa bora titi d'asiko ti wọn fi f'oju wọn ba'le-ẹjọ yii, ti wọn si lu alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Cranes Manufacturing to wa nilu Amẹrika.

Wọn ni ninu oṣu kẹrin ọdun to kọja, iyẹn 2019 ni awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa  fọrọ ọhun to ileeṣẹ FBI leti, t'awọn yẹn si kọ lẹta ifẹsunkan-ni, iyẹn petition EFCC si ajọ EFCC to gbogun ti iwa ajẹbanu.

Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe oṣiṣẹ EFCC, Idi Musa ti bẹrẹ iwadii, to si pada rii pe iya ati ọmọ ni wọn wa nidii iwa buruku naa. Banki la gbọ pe wọn ti mu iya Damilọla l'asiko to fẹ lọọ gba ninu owo yii, ti wọn si pada mu ọmọ rẹ

Onidajọ Chukwujekwu Aneke wa a paṣẹ pe k'awọn mejeeji lọọ fi ẹwọn gbara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI