Aawọ to wa laaarin Olubadan ti
ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji at'awọn Ọba ilu Ibadan tun ti gba ọna mi in yọ.
Ọjọbọ tii ṣe ọjọ kẹfa oṣu keji
ọdun yii ni Olubadan fi atẹjade kan sita, ninu eyi to ti sọ pe n ṣe loun ko ba
le awọn Ọba mọkalelogun kuro nilẹ Ibadan, ti oun ba tẹle ohun ti ọpọ ọmọ ilẹ
Ibadan n sọ.
Amọ ọkan lara awọn Ọba
mọkalelogun, Lekan Balogun to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe, isọkusọ gbaa ni
Olubadan n sọ, ko si si ẹni to dan iru rẹ wo ri.
Ọba Balogun ni Olubadan ko
lagbara bii ti wulẹ ko mọ, lati le awọn Ọba Ibadan kuro nilẹ Ibadan.
Balogun ni o ti le logoji ọdun
ti oun ti wa lori oye niluu Ibadan, bẹẹ ni oun ko ti ri Olubadan to dan iru rẹ
wo ri.
''Lati ọdun 1863 lawọn baba nla temi temi ti wa niluu Ibadan, wọn jọ tẹ Ibadan do ni, ẹba ọdan ni wọn n pe nigba naa, nitori naa ko si ẹni to le le mi kuro ni Ibadan,'' Oloye Balogun lo sọ bẹẹ.
O fikun ọrọ rẹ pe, awọn Ọba
mọkalelogun gan an lo lagbara lati yọ Olubadan nipo, Olubadan ko lagbara lati
yọ awọn Ọba ilu Ibadan.
Balogun sọ di mimọ pe, awọn
eeyan kan ni wọn n ti Olubadan lati ṣe ọpọ ohun to n ṣe, kii ṣe wi pe Olubadan
fun ra rẹ gan lo n daa ṣe awọn ohun to n ṣe.
O ni "danwo lo bi iya
ọkẹrẹ, ti Olubadan ba sọ pe oun fẹ le awọn Ọba mọkalelogun, a jẹ wi pe o fẹ pin
Ibadan si meji niyẹn, oun si lo maa jọba lori eyi to kere ju, ti ilẹ Ibadan ba
fi pe meji.
Olubadan sọ ninu atẹjade to fi
sita l'Ọjọbọ pe, awọn Ọba mọkalelogun yaju si itẹ oye Olubadan, ninu lẹta ti
wọn kọ ranṣẹ si oun lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kinni ọdun.
Ṣugbọn Oloye Lekan Balogun ni
ko si ohun to buru kankan ninu iwe tawọn fi ṣọwọ si Olubadan, o ni awọn kan pe
akiyesi rẹ si awọn nnkan kan to ṣe, ti ko dara ni.
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment